Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Bi idibo apapọ orileede yi ti
ṣe sunmọ etile, iyẹn ọjọ Satide ọla, apapọ ẹgbẹ oṣelu ti ko din ni ọgbọn labẹ
asia ẹgbẹ Conference of Nigeria Political Parties (CNPP), ẹka tipinlẹ Ogun
lawọn ti ṣetan lati gbarukuti adije sipo Sẹnetọ Aarin Gbungbun ipinlẹ Ogun (Ogun
Central) labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, Ọnarebu Titi Oseni-Gomez.
Eyi wa lẹyin ipade to waye
laarin awọn ẹgbẹ naa niluu Abẹokuta lọjọ Tọside ana, nibi ta a ti gbọ pe awọn
ẹgbẹ naa ṣepade lati gbarukuti obinrin to ti figba kan ri jẹ abẹnugọn ile
igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, lati le fi tako Gomina Ibikunle Amosun toun naa n
dije fun ipo kan ṣoṣo yii.
Nigba to n b’AWIKONKO sọrọ,
akọwe fidihẹ ẹgbẹ naa, Alaaji Akinyẹle Ṣarafadeen Ogunwọọlu sọ pe ko si nnkan
to jẹ kawọn fẹẹ fa obinrin naa kalẹ bi ko ṣe ipa to ti ko lasiko to fi wa
nijọba, paapaa bo ṣe ran ọpọlọpọ awọn ọdọ lọwọ.
Alaaji Ogunwọọlu ni akaimọye
awọn eeyan ni Titi Oseni-Gomez gbe dide lati ri iṣẹ kaakiri ẹka eto ijọba, ti
wọn si wa lẹnu iṣẹ titi dasiko yi, ati pe pupọ ninu awọn eeyan lo tun ro
lagbara ninu eyikeyi iṣe ti wọn yan laayo.
O tun fidi ẹ mulẹ pe ẹni to ṣe
e fọkan tan ni Titilayọ Oseni-Gomez, idi ni yii tawọn fi panupọ lati dide
iranlọwọ fun un, tawọn yoo si rii daju pe, obinrin naa de ipo lati lọọ ṣoju
awọn ara ẹkun Aarin Gbungbun ipinlẹ Ogun lọdun 2019 yi.
O lawọn ti pa a laṣẹ fun gbogbo
awọn ẹgbẹ naa pe ki wọn bawọn eeyan wọn sọrọ lati dibo fun Titi Oseni lọla tii
ṣe Satide tidibo fẹẹ waye, nitori pe latigba tawọn obinrin ti n ṣoju, wọn kii
ṣe magomago bi awọn ọkunrin.
Bakan naa nigba toun naa n
sọrọ, Alukoro ẹgbẹ naa, Ọnarebu Ṣẹgun Mathew naa fidi ẹ mulẹ pe lootọ lawọn ti
panupọ lati ṣagbatẹru obinrin naa fun ipo to n lọ, idi ni pe awọn nigbagbọ to
daju ninu ẹ.
O wa a rọ awọn ẹgbẹ oṣelu to ku
pe ki wọn gbaruku ti Ọnarebu Oseni-Gomez lati jade lọpọ yanturu, ki wọn si dibo
fun.
Bẹẹ lo rọ ajọ eleto idibo, iyẹn
INEC lati ma ṣe magomago ninu eto idibo apapọ naa, ki wọn si ma ṣe ṣoju-ṣaaju
nipa siso bi idibo naa ṣe lọ si, lati le dẹkun wahala ti yoo tidi ẹ yọ.
Lakotan, ọkunrin naa tun rawọ
ẹbẹ si sawọn Komiṣana mẹrin ti yoo ṣakoso eto idibo to fẹẹ waye naa, paapaa CP
Gbenga Adeyanju toun wa lẹkun Ogun Central pe ki rii pe wọn daabo bo ẹmi ati
dukia awọn araalu, paapaa lati ma ṣe jẹ kawọn to ti n gbero lati ji apoti idibo
gbe ri ọwọ mu.
No comments:
Post a Comment