Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Ṣe lawọn eeyan kawọ mọri, ti wọn sunkun ikunlẹ abiyamọ lọjọ Sande ana nigba ti ijamba mọto fẹmi eeyan ti ko din ni mejila ṣofo danu lagbegbe Ṣiun, lopopona Abẹokuta siluu Ṣagamu.
Ohun ta a gbọ ni pe ni nnkan bi
aago kan ọsan geerege ni taya mọto ayọkẹlẹ KIA SERATO kan wa lori ere deede fọ
danu, ti awakọ naa si n gbiyanju lati da a duro lojiji, to si mu ki mọto naa
sọda sodikeji lọọ kọlu bọọsi ati ọkọ ayọkẹlẹ min in to n bọ.
A gbọ pe opopona Ṣagamu ni mọto KIA SERATO ti wọn loo ko eeyan
mẹta ti n bọ, bo si ṣe e de agbegbe Ṣiun nijamba naa ṣẹlẹ, ta a gbọ pe o sọda
lọọ kọlu awọn mọto to n bọ lati Abẹokuta.
Awọn ẹṣọ oju popona, TRACE ati
FRSC la gbọ pe wọn palẹmọ awọn oku naa
lọ si mọṣuari, ti wọn si gbe awọn to farapa lọ si yara ti wọn ti n tọju awọn to
niṣẹlẹ pajawiri fun itọju, iyẹn ti Ọlabisi Ọnabanjọ to wa niluu Ṣagamu.
No comments:
Post a Comment