Olori ile igbimọ aṣofin agba
lorileede Naijiria, Sẹnetọ Bukọla Saraki ti jẹ ko di mimọ pe pipadanu toun
padanu kii ṣoju lasan, o lọwọ oṣelu ninu, ati pe kudiẹ-kudiẹ to wa lati ọdọ ajọ
eleto idibo ko ṣẹyin boun ṣe padanu ibo to waye kọja yi.
Bakan naa lo tun ṣalaye awọn
idi ti oun atawọn oludije ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara ṣe fidirẹmi, ninu eto
idibo apapọ to waye lọjọ Satide.
Saraki sọ eyi di mimọ ninu
atẹjade kan to fi sita, to fi ki awọn to gbe'gba oroke nibi eto idibo naa ku
oriire.
Saraki ni, bi o tilẹ jẹ wi pe
alaafia jọba lasiko idibo naa, sibẹ aikun oju oṣuwọn awọn ẹrọ ayẹkaadi idibo
wo, titẹka kọja iye ibo to yẹ atawọn iwa aitọ miran kaakiri awọn ibudo idibo ni
ipinlẹ naa, kun ohun to faa ijakulẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara.
Dokita Saraki ni, oun ki gbogbo
awọn ti INEC kede gẹgẹ bii olubori ku oriire ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu oun yoo gbe
igbesẹ to ba tọ, nigba to ba ya lori awọn kudiẹkudiẹ naa.
"Gẹgẹ bii ẹni to wa lati
inu ẹbi ati eto oṣelu to gbilẹ lati ibẹrẹ pẹpẹ ninu iṣiṣẹ sin araalu ati
idagbasoke awọn eniyan rẹ, ireti mi ni pe awọn eeyan wa yoo maa ri ere pipe ni
igba gbogbo.
Ohun to ṣẹlẹ yii yoo tilẹ tun
fun awọn eeyan lanfani ati gbe ẹgbẹ mejeeji si ẹgbẹ ara wọn fun ayẹwo ati
afiwe. Ju gbogbo rẹ lọ awọn to bori ni idibo satide kii ṣe ọta mi. ọmọ ipinlẹ
Kwara kan naa bii temi ni wọn jẹ."
Ibrahim Oloriẹgbẹ lo gbẹyẹ mọ
Saraki lọwọ ninu idije fun ijoko aṣofin agba, fun ẹkun idibo guusu ipinlẹ Kwara.
No comments:
Post a Comment