Ko sẹni to wa niluu Benin laipẹ yi, paapaa lagbegbe ti wọn ti yinbọn pa baale ile kan ta a ko tii mọ orukọ ẹ titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan, ẹni ti wọn sọ pe ibi to jokoo si nibọn ti lọọ ba a, ti omije ko nii bọ loju ẹ, pẹlu bawọn mọlẹbi ẹ ṣe n wa ẹkun mu.
Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji nni,
Eye ati Aye la gbọ pe wọn kọju ija sira wọn nibi ti ọkunrin naa nileeṣẹ to ti n
bawọn eeyan fọ mọto.
Bi wọn ṣe yinbọn pa baale ile
naa la gbọ pe awọn to wa nitosi fẹsẹ fẹẹ, tawọn to ni ṣọọbu lagbegbe naa si sare
ti ṣọọbu wọn, igba tọrọ naa lọ silẹ la gbọ pe awọn eeyan ṣẹṣẹ bẹrẹ sii pada
yọju sibẹ.
Awọn tọrọ naa ṣoju wọn lo ranṣẹ
pe awọn mọlẹbi ọkunrin naa lati wa a gboku ẹ. A gbọ pe ọkunrin naa lo n gbọ
bukata lori awọn mọlẹbi ẹ.
No comments:
Post a Comment