Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Pẹlu
ọrọ ti adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APM, Ọnarebu Adekunle Akinlade sọ nipa
ipo tipinlẹ Ogun wa lonii, afaimọ ko ma jẹ pe Gomina Amosun yoo pada lẹyin
ọkunrin naa nitori pe kayeefi lọwọ naa ṣi n jẹ leti gbogbo awọn araalu, paapaa
awọn to wa nibi ipade itagbangba fawọn gomina, eyi ti ileese BBC Yoruba
ṣagbekalẹ ẹ.
Ọnarebu
Adekunle Akinlade tawọn eeyan tun n pe ni Triple A, ẹni ti gomina Amosun fa
kalẹ lati tako adije ti ẹgbẹ oṣelu APC fa kalẹ, iyẹn Ọmọba Dapọ Abiọdun lo bu
ẹnu atẹ lu ijọba gomina Amosun, to si ni inu awọn araalu gan an ko dun si ipo
tipinlẹ naa wa.
Ninu
ọrọ ẹ, Akinlade ni, “Mo fe ko da wa loju, mo si ti n so kaakiri gbogbo ibi ti
mo ti de pe, ni gbogbo awa adije patapata ta a wa nibi yi, emi ni kan ni mo ti
lo kaakiri woodu igba ati mokanla (211) lati ojo keji osu kinni odun yi titi dasiko
yi.
“Mo
fi n ye won, mo ti ri aini, mo ri ipo ainireti tawon eeyan wa wa, afi ti eeyan
ba je ika nikan leeyan maa so pe nibi ti mo ba de yi pe maa se sibi bayii, mi
o ni se sibi kan.”
Bi
Akinlade ṣe sọrọ naa tan, lawọn to eeyan to gbọ nnkan ti Akinlade sọ yi ti bẹrẹ
sii bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti ọkunrin naa sọ, ti wọn si n sọ pe alaimoore ni, nitori
pe ṣe lo dabi ẹni to wa a yẹyẹ ọga ẹ nita gbangba.
Ohun
tawọn min in tun sọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ pe asasi awọn ẹgbẹ alatako to mu ọkunrin
naa to fi sọ iru ọrọ bẹẹ jade sita, paapaa nigba ti adije sipo gomina labẹ egbe
oṣelu African Democratic Congress, ADC, Ọmọba Gboyega Isiaka naa dupẹ lọwọ ẹ pe
inu oun dun nitori pe o sọ otitọ ọrọ, ko si fi bo rara.
No comments:
Post a Comment