Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Akarigbo tilẹ Rẹmọ, Ọba Babatunde Adewale Ajayi ti sọ pe gbogbo agbara to ba wa nikawọ oun loun yoo lo lati rii pe idagbasoke de ba ipinlẹ Ogun, paapaa nipa igbodegboke ọkọ.
Ọba Ajayi lo sọrọ naa lasiko to
n gba awọn igbimọ to n ri si igbokegbodo ọkọ nipinlẹ naa lalejo ni aafin ẹ to
wa niluu Ṣagamu laipẹ yi.
Kabiyesi naa ni pẹlu ipo oun
ati boun ṣe mọ awọn ọlọla kaakiri agbaye to, paapaa boun tun ṣe jẹ Ọba alaye
nilẹ Rẹmọ, oun yoo rii pe awọn nnkan to le mu kawọn to n da ileeṣẹ nla-nla silẹ
loun yoo gbe kalẹ.
Awọn igbimọ to n ri si
igbokegbodo ọkọ, iyen State
Bureau of Transportation (BOT) nipinlẹ Ogun la gbo pe wọn loo sabẹwo si Kabiyesi Akarigbo lati
yẹ awọn bọọsi nla-nla to ṣẹṣẹ ra fun igbokegbodo awọn araalu wo, ati bawọn
araalu ṣe tẹwọ gba a si.
Ninu ọrọ ti ẹ,
amugbalẹgbẹ Gomina ipinlẹ Ogun lẹka igbokegbodo ọkọ, Amofin Gbenga Opẹsanwo ti
Onimọ-ẹrọ Wale Ṣokunbi ṣoju fun gbe oṣuba kare fun Akarigbo latari bo ṣe da si
ipenija to n koju igbokegbodo awọn araalu.
No comments:
Post a Comment