Bo tilẹ jẹ pe AWIKONKO ko tii fidi ẹ mulẹ boya Ọnarebu Abiọdun ajayi ti gba lati du ipo aṣoju-sofin niluu Abuja lẹkun Abẹokuta South, ṣugbọn pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yi, o ṣee ṣe ko jẹ pe ọkunrin naa ni yoo di aṣoju-ṣofin labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo to n bọ lọjọ Satide yi.
Ohun ta a gbọ ni pe latigba ti
adije ti wọn dibo abẹle yan, Ọnarebu Owolabi Balogun ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu
PDP nipinlẹ Ogun, to si loun ko dupo naa mọ lawọn eeyan ninu ẹgbẹ naa ti n sọ
pe ki Ọnarebu Abiọdun Ajayi gba ipo naa.
Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ
ninu ẹgbẹ oṣelu naa, wọn yoo mọ pe Abiọdun Ajayi lo ṣe ipo keji ninu idibo
abẹle to waye lọdun to kọja, latigba naa lo si ti lọọ jokoo, iyẹn nigba to gba
kamu.
Ajayi to ti figba kan ri jẹ
alaga ijọba ibile ri ni wọn lawọn agbaagba lẹgbẹ naa ti n parọwa si pe ko gba
ipo naa pada, nitori pe oun gan an lẹni tawọn nifẹ si lati ṣe e, ati pe asiko
naa re e ti yoo di aṣoju-ṣofin.
Kii ṣe tẹnu pe bi Ajayi ba gba
ipo naa, oun lawọn eeyan yoo dibo fun un bo lasiko idibo to n bọ naa, nitori pe
awọn eeyan ko tii gbagbe ipa to ko lasiko to wa nipo alaga ijọba ibilẹ.
Nigba to n ba ọkan lara awọn
akọroyin to firoyin to wa leti, Ọgbẹni Azeez Fufilẹ toun n gbe ladugbo Itoko
niluu Abẹokuta sọ pe inu oun yoo dun bi Ọnarebu Ajayi ba gba tete gba ipo naa,
nitori pe idibo ti sunmọ etile.
O lawọn nigbagbọ to daju ninu
Ajayi, eyi to mu kawọn sa gbogbo ipa ati agbara fun un lati rii pe wọn dibo yan
an.
No comments:
Post a Comment