Alaga ẹgbẹ CNPP, iyẹn Conference of Nigeria Political Parties, Ọtunba Owolabi Odebudo ti sọ ọ sita gbangba pe gbogbo eto lo ti pari lati fun adije sipo sẹnetọ labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, Ọnọrebu Titi Oseni-Gomez ni ibo ti ko din ni miliọnu kan lọjọ Satide ọla.
Ọtunba Odebudo lo fidi ọrọ naa mulẹ lonii Fraide lasiko
to n ba akọroyin AWIKONKO sọrọ niluu Abẹokuta, o ni gbogbo nnkan tawọn nilo lo
ti wa nilẹ bayii lati rii pe Titi Oseni-Gomez jawe olubori ninu ibo to n bọ
naa.
Ẹgbẹ CNPP ta a gbọ pe ko din ni ẹgbẹ oṣelu mọkandinlọgbọn
lo wa labẹ ẹ.
Ninu ọrọ alaga naa, o ni latari ipade alaafia ti ẹgbẹ naa
ṣe laipẹ yi, awọn ti fimọ ṣọkan laarin ara wọn lati ri i pe Oseni-Gomez to ti
figba kan ri jẹ abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ninu ijọba to kọja lọ.
O ni ko din ni milọnu kan oludibo lawọn ti yoo dibo fun
Ọnọrebu Titi Oseni-Gomez lọjọ Satide ọla ti idibo apapọ yoo waye, nitori pe oun
gan an lẹni to kaju ẹ lati ṣe e.
Nigba to n sapejuwe obinrin naa, Ọtunba Odebudo sọ pe ko
sẹni ti ko ri ipa ẹ lasiko to fi wa nijọba, nitori pe pupọ awọn araalu ni wọn
jẹ anfaani ẹ nigba naa, ti ipa ẹsẹ ko si le parẹ titi lai ni Aarin gbungbun
ipinlẹ Ogun.
O wa a rọ ileeṣẹ ologun atawọn ọlọpaa, to fi mọ gbogbo
eleto aabo ti wọn ti gbaradi fun idibo naa lati ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ, ki wọn si ri i
pe wọn fiya jẹ awọn tọọgi ti wọn ba gbiyanju lati ji apoti ibo gbe gẹgẹ bi aṣẹ
Aarẹ Muhammadu Buhari.
No comments:
Post a Comment