Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe
awọn ko ni ti ọna kankan pa lasiko abẹwo Aarẹ Muhammadu Buhari si ipinlẹ naa.
Ikede yii jẹ iyipada ikede ti
wọn ti saaju fi sita pe awọn oju ọna kan yoo wa ni titi pa nigba ti Aarẹ Buhari
ba wa fun ipolongo idibo ni papa iṣere agbegbe Surulere lọjọ ti.
Komisana fun irina nipinlẹ Eko
Ladi Lawanson ṣalaye loju opo Twitter ijọba Eko pe iyipada yi waye lẹyin ti
awọn ṣe agbeyẹwo eto irina ti wọn ti ṣe tele ti wọn si tẹti si ohun ti ara ilu
sọ.
Inu fo aya fo lawọn ara ilu Eko
kan wa lati igba ti ijọba kede titi awọn oju ọna kna pa nitori abẹwo Aarẹ
Buhari sipinlẹ naa.
Lọpọ igba ti awọn alaṣẹ pataki
bi Aarẹ ba ṣe abẹwo si ipinlẹ Eko ni inira ma a n ba ara ilu nipasẹ sunkere
fakere ọkọ ti o ma n tele iru abẹwo bẹẹ.
Bi a ko ba gbagbe, ijọba ipinlẹ
Eko ya ọjọ ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, Osù Kẹẹ̀ta ọdun to kọja gẹ́gẹ́bí ọjọ́ Ìsinmi
fún àwọn òsísẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà lasiko ti Aarẹ Buhari ṣe abẹwo sipinlẹ naa lati
ṣe ifilọlẹawọn akanṣe iṣẹ kan.
Toun ti ikede yii, awọn to jade
lawọn agbegbe kan ke irora latari sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ to waye.
- BBC
No comments:
Post a Comment