Olùdarí
fún Àjọ náà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Arábìnrin Dọlápọ̀ Aya Dosùnmú ló sípayá ọ̀rọ̀ yìí níbi ètò
ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan lórí ohun tó yẹ kí àwọn olùdìbò mọ̀ nínú ìdìbò èyí tó wáyé lọ́gbà
Yunifásitì Ìbàdàn láìpẹ́ yìí.
Ó ní ohun
kan tó sẹ kókó nínú ètò ìdìbò ni kí àwọn olùdbò tẹ̀ka sí ibi tó yẹ lórí ìwé ìbò
nítorí náà ni ó ṣe yẹ kí àwọn olóṣèlú mú ṣíṣe àgbéklalẹ̀ ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn
ará ìlú pàápàá àwọn alátìlẹ́yìn wọn lókùúkúndùn.
Ó ṣàlàyé
pé ètò ìdìbò ilẹ̀ wa ní ìlànà à-ń-tẹ̀lé pàápàá dídi ìbò fún adíje kan ní ibùdó
ìdìbò.
Ó tẹ̀síwájú
pé ìmọ̀ bí a ṣe ń tẹ̀ka yìí nìkan ló lè gba ètò ìdìbò ilẹ̀ wa lọ́wọ́ àwọn ìbò
tí àwọn ìbò tí kò ṣéegbà, pẹ̀lú àfikún pé irúfẹ́ àwọn ìbò tí àjọ tó ń sètò
ìdìbò máa kò wọ̀nyí máa ń ṣe àkóbá fún àwọn olóṣèlú tí ó yẹ kó jáwé olúborí.
Olùdarí
ọ̀ún wá pé àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú níjà láti mú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà mọ́ ètò ìpolongo wón
pẹ̀lú àfikún pé olóṣèlú tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó bá kọ̀ láti ṣe èyí kò nífẹ̀ẹ́ àwọn
ará ìlú dọ́kàn bí kò ṣe àtirí ìbò wọn nìkan ló wà lọ́kàn irú olóṣèlú àti ẹgbẹ́
òṣèlú bẹ́ẹ̀.
Ó ní
iṣẹ́ ìtanijí àwọn ará ìlú lórí bí ó ṣe yẹ kí wọ́n dìbò náà kìí ṣe iṣẹ́ àjọ ọ̀ún
nìkan bíkòṣe iṣẹ́ gbogbo adíje àti ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń díje pẹ̀lú pé kí wọ́n ṣíṣe
èyí níbi àwọn ìpolongo wọn nìkan ló lè rí i dájú pé wọn kò fi ìbò ṣòfò.
Aya Dọlápọ̀
wá rọ àwọn ará ìlú láti tẹ̀lé àwọn ìlànà ìdìbò pàápàá rírí i pé wọ́n tẹ̀ka
síwájú àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n fẹ́ dìbò fún kí wọ́n má sì jẹ́ kí ó bọ́ sórí ti
ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn.
No comments:
Post a Comment