WỌ́N TI DÁ ÀWỌN ỌMỌ NÀÍJÍRÍÀ MÈJÌLÉLÀÁDỌ́JỌ PADÀ LÁTI LIBYA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 31, 2019

WỌ́N TI DÁ ÀWỌN ỌMỌ NÀÍJÍRÍÀ MÈJÌLÉLÀÁDỌ́JỌ PADÀ LÁTI LIBYA


Kò dín ní mèjìlélàádọ́jọ àwọn ọmọ ilẹ̀wa, Nàíjíríà tí wọ́n ti gúnlẹ̀ sí ilẹ̀ baba wọn láti Libya níbi tí wọ́n ti gbé ṣe àtìpó ní àná Ọjọ́rú Wẹ́sìde.

Díde àwọn ọmọ ilẹ̀ wa yìí ló jé ara itẹ̀síwájú ipa tí àjọ iṣòkan Yúróópù àti àjọ tó ń rí sí ìwọléjáde àwọn ènìyàn láti orílẹ̀ èdè kan sí kejì lágbàyé, EU/IMO ń kó láti mú àwọn ọmọ ilẹ̀ wa tí wọ́n há sí Orílẹ̀ Èdè Libya padà.

Ní òwúrọ̀ Ọjọ́rú, àná ni àjọ tó ń rí sí ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì nílẹ̀ wa, NEMA tẹ́wọ́gbà wọ́n ní pápákọ̀ òfurufú Murtala Muhammed ní ìlú Èkó.

Olùdarí àjọ NEMA ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Alhaji Idris Muhammed ṣàlàyé pé obìnrin ọgọ́rùn-ún nínú èyí tí àwọn aláboyún mẹ́rin wà nínú wọn àti àwọn ọkùnrin méjìlélàádọ́ta ọkùnrin ni ó padà láti Orílẹ̀ Èdè Libya.

Àtúpalẹ̀ iye àwọn ènìyàn náà fihàn pé mẹ́tàlá ni iye àwọn ọmọbìnrin, márùn-ún ni àwọn ọmọ ọwọ́ lọ́bìnrin nígbà tí iye àwọn abílékọ jẹ́ èjìlélọ́gọ́rin. Iye àwọn ọkùnrin jẹ́ àádọ́tá, tí àwọn ọmọkùnrin jẹ́ mẹ́rin nígbà tí àwọn ọmọ ọwọ́ lọ́kùnrin jẹ́ mẹ́tàlá.

Olùdarí náà wá rọ àwọn ẹnílọlọ́bọ̀ yìí láti mú àyípadà rere wọ ayé wọn, kí wọ́n sì máa fọn rére àwọn ewu tó wà nínú ìrìnàjò sókè òkun lọ́nà àìtọ́ fún àwọn tó bá fẹ́ hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.

Ètò kíkó àwọn ọmọ ilẹ̀ wa padà láti ilẹ̀ Libya, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lósù kẹrin, ọdún 2017 ti yóò sì dópin ní oṣù kan náà lọ́dún 2020, ti mú ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè wa padà láti ìlú náà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI