WỌN LU PASITỌ PA L'EKITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 23, 2019

WỌN LU PASITỌ PA L'EKITI

Ṣe lo dabi ẹni pe awọn ara ipinlẹ Ekiti ti gboro bayii, pẹlu bi wọn ṣe n lu awọn ẹlẹṣẹ tọwọ palaba wọn ba segi.

Laipẹ yi lọwọ awọn gendenkunrin ladugbo ti wọn n pe ni Mathew, iyẹn lagbegbe Apata Iṣẹgun tẹ pasitọ ṣọọṣi Kerubu ati Serafu to wa ladugbo naa. 

Igbẹ eeyan la gbọ pe wọn ka mọn ọn lọwọ nibi to ti fi n jẹ burẹẹdi.

Kaakiri adugbo naa la gbọ pe wọn mu pasitọ naa yipo, bi wọn si ṣe n mu kaakiri ni wọn n luu. Igba ti wọn luu daadaa ni wọn too ṣẹṣẹ muu gba ṣọọṣi ẹ lọ nibi ti wọn luu pa si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI