Ile ẹjọ majisireeti to fikalẹ siluu Akurẹ nipinle Ondo ti
paṣẹ pe Ọba Oluwambẹ Ọjagbohunmi tiluu Ayetoro nijọba ibilẹ Ilajẹ ṣi lọ maa
gbatẹgun lọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹrinlelogun oṣu yi latari ẹsun idigunjale ati
dida wahala silẹ laarin ilu ti wọn fi kan an.
Ade Ọba |
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni Kabiyesi naa atawọn kan awọn ti
na papa bora lọọ digun jale pẹlu ibọn, ada atawọn nnkan ija oloro. Awọn eeyan
marun-un ọtọọtọ la gbọ pe Kabiyesi atawọn ẹmẹwa ẹ lọ ọ digun ja lole obitibiti
owo ati dukia laipẹ yii.
Yatọ si eyi, agbẹjọro fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni
Ọlatunji Kazeem to fẹsun kan Ọba Ọjagbohunmi sọ pe ẹsun ti ileeṣẹ wọn fi kan
Ọba naa tako ofin lilo ibọn lorileede yi tọdun 2004.
O ni yatọ sawọn ti Ọba Ọjagbohunmi atawọn ẹmẹwa ẹ ja lole
yi, wọn tun lọ ọ gbimọ pọ ja ọkunrin l’ole owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna aadọjọ
(160,000), bẹẹ ni wọn tun ji ẹrọ amunawa, iyẹn jẹnẹretọ ẹ.
Bẹẹ lo tun sọ pe Kabiyesi atawọn eeyan ẹ yi tun yinbọn
fun ọkunrin kan ti wọn pe ni Olu Obolo ni ẹsẹ lasiko ti wọn n fa wahala, o ni
gbogbo ẹsun yi lo tako iwe ẹsun ọdaran tipinlẹ Ondo, t’ọdun 2006.
O wa rọ ile ẹjọ naa lati ma gba jẹ ki ẹnikẹni gba beeli
Kabiyesi naa digba ti wọn yoo tubọ fi pari awọn iwe ẹsun e.
Adajọ ile ẹjọ naa, Onidajọ Mayọmi Ọlanipẹkun wa a paṣẹ
pe kawọn ọlọpaa ṣi lọ ọ fi Ọba alaye naa pamọ sọdọ wọn titi di ọjọ kẹrinlelogun
oṣu yi, igbẹjó min-in yoo waye.
No comments:
Post a Comment