Bi kii ba a ṣe pe ori to wa lẹyin baale ile kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Shehu
Adamu ni, o ṣe e ṣe kile ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Abuja ti sọ ọ sẹwọn
latari ẹsun tawọn ọlọpaa fi kan an pe o funra rẹ ji mọto ara rẹ gbe ni teṣan wọn,
lai jẹ kawọn ọlọpaa mọ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, laipẹ yi ni wọn lawọn ọlọpaa da Shehu duro, nigba ti wọn
beere ọrọ lowọ ẹ la gbọ pe wọn sakiyesi pe Shehu ko iwe irina, iyẹn drivers
licence, idi ni yii ti wọn fi gbe mọto Shehu lọ si teṣan wọn.
Ko pe la gbọ pe Shehu tun lo ọgbọn arekereke ;ati lọọ gbe mọto naa kuro lai
jẹ kawọn ọlọpaa mọ, lẹsẹkẹsẹ taṣiri ti
tu lawọn ọlọpaa naa ti lọ ọ foju ẹ bale ẹjọ.
Gbogbo ẹsun ti wọn fi kan Shehu niwaju adajọ naa lo sọ pe oun gba pe oun jẹbi
awọn ẹsun, nitori naa, o bẹbẹ pe kile ẹjọ fi oju aanu wo oun, ki wọn ba oun din
ijiya to tọ soun ku.
Ṣugbọn nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ naa, Arabinrin Ijeoma Ukagha ni
ki Shehu maa lọ ni ayọ ati alaafia, ki o si rii daju pe oun ko tun hu iru iwa bẹẹ
mọ laye ẹ.
No comments:
Post a Comment