OWO OṢU TUNTUN: AWỌN OṢIṢẸ YARI LORI ẸGBẸRUN MẸTADINLỌGBỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 22, 2019

OWO OṢU TUNTUN: AWỌN OṢIṢẸ YARI LORI ẸGBẸRUN MẸTADINLỌGBỌN


Agbarijọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede yi ti fariga pe awọn ko ṣetan lati gba ẹgbẹrun mẹtadinlọgbọn (27,000) naira owo oṣu tuntun tijọba apapọ sọ pe awọn yoo maa san fawọn oṣiṣẹ gẹgẹ bi owo oṣu tuntun.

Onii Tuside la gbọ pe wahala bẹ silẹ laarin awọn agbaagba ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ atawọn tijọba yan lati dari ipade naa. Akọwe agba, Dokita Peter Ozo-Eson lo fi ọrọ yi naa sita lẹyin ipade ti wọn ṣe, eyi to fori sanpọn.

Okunrin naa fi ẹdun ọkan ẹ han sita,o sọ pe o ṣeni laanu pe igbimọ tijọba apapọ gbe kale lati ri si ọrọ owo oṣu naa ko ṣe nnkan tawọn oṣiṣẹ n fẹ, wọn ko sọrọ sibi ti ọrọ wa, ọtọ ni nnkan ti wọn sọ lẹnu.

O ni ko yẹ kijọba maa da nnkan ti ko pẹ duro, ki wọn si maa sun ọrọ owo oṣu ti ko gba wahala siwaju, ko si tun wa a jẹ pe owo ti ko to nnkan ni wọn ma a gbe wa siwaju awọn lati gba a.
 
Ozo-Eson wa a sọ pe awọn ti sun ipade miran si ọjọ Fraide to n bọ yii lati mọ ibi tawọn yoo fori o\rọ naa ti si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI