Ọba Fatai
Akorode Akamọ, Olu Itori tiluu Itori nijọba ibilẹ Ewekoro ti gbe oṣuba kare fun
ijọba apapọ orileede yi latari eto ounjẹ ọfẹ ti wọn gbe kale fawọn akẹkọọ
nileewe alakọbẹrẹ kaakiri orileede yi, paapaa nipinlẹ Ogun, eyi ti wọn pe ni
National Home Grown School Feeding Programme (NHGSFP).
Kabiyesi lo
gboriyin yi lasiko to n gba awọn aṣoju ti wọn ran lati wa a ṣabẹwo sawọn ileewe
to wa nijọba ibilẹ naa lalejo ninu aafin ẹ laipẹ yii. O ni ipinu alaragbayida
ti ko lafiwe ni, ati pe agbekale eto naa jẹ ilana idagbasoke l’ẹka eto ẹkọ.
Bakan naa lo
sọ pe eto naa ti jẹ kawọn akẹkọọ maa pọ daadaa nileewe, nitori ti wọn gbagbọ pe
awọn yoo ri ounjẹ to ṣe ara loore jẹ bawọn ba ti de ileewe.
Ninu ọrọ ti ẹ, alakoso eto naa, Ọgbẹni Dọtun Adebayọ dupẹ lọwọ
Kabiyesi latari bo ṣe gba wọn laaye ninu aafin naa. O ni nipa agbekalẹ eto naa,
ipinlẹ Ogun jẹ akọkọ ninu awọn ipinlẹ to kọkọ jẹ anfaani ẹ.
AWIKONKO gbọ pe ko din ni ẹgbẹrun mẹta awọn olounjẹ lawọn ti wọn n jẹ anfaani eto naa, to si din iṣẹ ati oṣi ku lawujọ wa.
No comments:
Post a Comment