Aarẹ tẹlẹri lorileede yi, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti s’ọko ọrọ sita fawọn
agbaagba ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress lorileede yi pe bi wọn ba yẹ iṣẹ ọwọ
gbogbo wọn wo, bi wọn ba gbe iṣẹ wọn sori oṣuwọn, ọrun apaadi ni gbogbo wọn n lọ.
Oloye Ọbasanjọ lo sọrọ naa lasiko ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣe BBC ti ede
Yorubato laipẹ yi. Bo ṣe fi erongba rere ẹ han fun Alaaji Atiku Abubakar toun
jade dupo Aarẹ orileede yi labẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples’ Democratic Party, PDP.
Ẹbọra Owu sọ pe lootọ oun ko so pe eeyan gidi ni Atiku, ṣugbọn yoo ṣe
daradara ju Aare Buhari lọ. Ẹlẹṣẹ pọnbele lawọn oloye ẹgbẹ oṣelu naa.
Ninu ọrọ Baba Iyabọ, O ni “Bi a ba n sọrọ nipa ẹṣẹ, awọn ti wọn wa nibẹ
bayii, bi a ba yẹ wọn wo daadaa, inu ina ni gbogbo wọn n lọ.
“Kii ṣe pe wọn kan maa ju wọn sinu ẹwọn lasan, wọn maa tun wọnu ina apaadi.
Ẹni ti Ọlọrun ba ba bo ẹṣẹ mọlẹ, awọn aṣiri ẹ maa wa labẹ idaabobo.
“Mi o sọ pe bi Atiku ba de bẹ, o maa ṣe bi Jesu tabi Mohamẹẹdi, ṣugbọn yoo ṣe
daadaa ju nnkan ti a n ri bayii lọ.
“Ẹni to jẹ olori wa lonii ti sọ pe oun ko le ba ẹya min in ṣiṣẹ papọ nitori
pe oun ko le finu tan wọn. Ti ko ba si le finu tan ẹya mi tabi ẹya yin, ki wa
ni anfaani ẹ? Atipe o tun n sọ pe ki ẹya emi ati yin wa a dibo foun.
“O le beere fun ibo wa, ṣugbọn ko le nigbagbọ ninu wa lati ṣiṣẹ lawọn ibi
to dara. Gba fun Muri ni gba fun gbada, bẹẹ gẹlẹ lọrọ ile aye. Bi o ko ba le
nigbagbọ ninu mi, ki lo de ti emi naa maa nigbagbọ ninu ẹ.
“Bi o ba fi mi sipo, ti mo si ṣe aṣiṣe, ki lo de ti ko le yọ mi kuro, ko si
fi ẹlomiran sii?
“Ṣugbọn awọn to n fi sipo, awọn ẹya ẹ nikan ni, nitori pe awọn nikan lo le
gbagbọ.”
No comments:
Post a Comment