Ijọba apapọ orileede Naijiria ti sọ pe awọn yoo gbe ọrọ
owo oṣu tuntun tawọn oṣiṣẹ n ja fun lọ siwaju ajọ to n ri sọrọ eto ọrọ aje,
iyẹn National
Economic Council lọjọ Tọside ọla yi fun agbeyẹwo siwaju sii.
Wọnyii lohun ti ijọba apapọ atawọn igbimọ ti wọn yan lati
dari eto naa, iyen Federal Executive
Council fẹnuko si lalẹ ọjọ Tuside ana ninu ilegbe Aarẹ to wa niluu Abuja.
Awọn gomina ipinlẹ, Banki apapọ orileede yi, atawọn
minisita tọrọ naa kan, to fi mọ awọn ileeṣẹ ijọba loriṣriṣi la gbọ pe wọn wa
ninu igbimọ (NEC) naa.
Gẹgẹ bi Minisita fọrọ iroyin, Alaaji Lai Mohammed ṣe sọ
fawọn akọroyin, o ni bo tilẹ jẹ pe oun ko le sọ pato nnkan tawọn ba bọ nibi
ipade naa, nitori pe iṣẹ ṣi n lọ lọwọ lori ẹ.
Lai Mohammed ni, o digba tawọn ba fori ọrọ naa ti, lawọn
yoo to o le sọrọ jade fawọn eeyan lati mọ.
No comments:
Post a Comment