Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Alaga patapata fun ẹgbẹ oṣelu United Democratic
Party, UDP, Oloye Austine Okoye, ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti Aarẹ orileede yi,
Ọgagun Muhammadu Buhari gbe latari bo ṣe yọ adajọ agba orileede yi, Onidajọ
Walter Ọnnọghẹn nipo lojiji latari awọn ẹsun ti wọn fi kan an pe ko jẹwọ gbogbo
dukia ẹ tan ki wọn too yan an.
Lọjọ Fraide ọsẹ to kọja yi ni Aarẹ Buhari kede
sita fawọn araalu pe oun ti jawe lọọ jokoo sile ẹ fun adajọ agba naa, eyi lo si
ti fa oriṣiriṣi wahala laari ẹka eto idajọ, oṣelu, bẹẹ lawọn eeyan
jankan-jankan naa ko dẹkun lati maa bu ẹnu atẹ lu igbesẹ Aarẹ naa.
Lọjọ Mọnde ana ni Oloye Okoye to jẹ alaga lapapọ
ẹgbẹ oṣelu UDP lorileede yi naa b’AWIKONKO sọrọ niluu Ọta nipinlẹ, nibi
ipolongo imurasilẹ idibo gomina to n bọ nipinlẹ Ogun, eyi ti wọn ṣe fun adije
sipo labẹ ẹgbẹ oṣelu naa, iyẹn Oloye Arabinrin Jackie Adunni Kassim, nibẹ lo ti
mẹnuba awọn iwa to ku diẹ kaato, eyi to n lọ lagbo oṣelu orileede yi.
Okoye sọ pe “Igbesẹ naa ko ba ilana ofin mu rara,
paapaa fun awa ta a jẹ agbẹjoro, ibanujẹ lo jẹ fun wa pe iru nnkan bayii n ṣẹlẹ
niru asiko ọlaju ta a wa yii, ati pe niru orileede Naijiria to n ri ara ẹ gẹgẹ
bi asiwaju awọn orileede ilẹ adulawọ (Afrika) ni wọn ti n tẹ ofin mọlẹ ṣibaṣibo.
“Gbogbo awọn ọmọ orileede Naijiria patapata ni
wọn gbọdọ dide niru asiko bayii lati ja fun ẹtọ naa, nitori pe nigba ti awọn
apaṣẹ ba de, awa ọmọ Naijiria yi ni yoo jiya ẹ. Nnkan to ṣẹlẹ yi jẹ ibanujẹ
pupọ fun ofin wa, to si tun jẹ itiju fun lilo agbara wa, ati fifi eto iṣejọba
awaarawa si ojuṣe.”
Nigba to n sọrọ lori ibẹrun awọn eeyan pe o ṣee
ṣe ki wọn yi ibo ọdun 2019, alaga naa sọ pe “Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yi, mi o ni
fẹ ẹ ka ẹnikẹni bo ya aya wọn n ja, nitori pe igi inu igbi nikan lo maa gbọ pe
wọn ge igi lẹgbẹ oun, to si tun maa duro, ko da bi aro, gan an ba gbọ pe wọn fẹ
ẹ pa oun, o maa wa gbogbo ọna lati salọ.
“Nnkan ta a ti ri atawọn nnkan ta n ri lojoojumọ lorileede
yi ti fi ye wa pe gbogbo nnkan lo ti bajẹ, asiko yi kii sii ṣe asiko tẹnikẹni
le maa sunnu si, asiko ipenija nla la wa lorileede yi, a si gbọdọ rii pe a
yanju ẹ daadaa, ki nnkan le pada bọ sipo, nitori pe ọpọ igba lati fi erongba wa
han nipa ofin to de ajọ aleto idibo, iyẹn INEC to tun jẹ pataki, nitori pe ọna
lati gbe ọkan kuro nibi to yẹ lawọn nnkan min in to n ṣẹlẹ lati ma jẹ kawọn
eeyan okodoro nnkan ta n koju.
“Bawo lẹ ṣe maa so fun mi pe eeyan wa a dibo, ero
ti wọn fi n yẹ kaadi wo ko da ẹni to ni kaadi mọ, ẹ si gba iru ẹni bẹe laaye
lati dibo, bawo lẹ ṣe maa sọ fun mi pe ẹni kan ji kaadi idibo yin, wọn si gba
yin laaye lati dibo, bawo lẹ ṣe maa mu agbegbe tawọn eeyan yoo ti dibo, tawọn
to wa lagbegbe naa ko si nii mọ.
“Wọn ni yiyẹ awọn ti yoo dibo ni kaadi idibo
alalopẹ, PVC wa fun, wọn tun ni awọn ilana kan wa tawọn eeyan yoo ṣe, ẹ ba mi
beere boya gbogbo ẹgbẹ oṣelu ni wọn mọ nipa ẹ. To ba wa a di ọjọ idibo, wọn a
wa maa sọ fawọn kan pe wọn ko lanfaani lati dibo, awọn kan ni wọn le dibo.
“Bawo lẹ ṣe fẹ ka gbagbọ pe wọn ko nii yi ibo,
awọn ti wọn si n ni ifura yi, mi o bu ẹnu atẹ lu wọn, nitori pe nnkan to dara
ni. Ti ajọ INEC ba mọ nnkan ti wọn n ṣe, ti wọn si ṣe e lasiko, lati da igboya
wọn pada sọkan awọn araalu, inu wọn yoo dun. Itẹsiwaju lo yẹ kijọba jẹ, ko nii
ṣe pẹlu ẹni to ba wọle, bi ẹ ba wọle, ẹ maa tẹsiwaju lati maa ṣe ifẹ ọkan awọn
ọmọ Naijiria.
“Bo ṣe yẹ ki nnkan maa lọ niyẹn, a n ja fun, a si
tun ma maa tẹsiwaju lati ja fun un ni.”
Bakan naa nigba to n sọrọ nipa bi ẹgbẹ naa yoo ṣe
gba ijọba lọdun 2019 ti a wa yii, paapaa nipinlẹ Ogun, Oloye Okoye ni “Bi ẹyin
naa ba ri bi nnkan ṣe n lọ, ẹ maa rii pe adije wa, Oloye Jackie Adunni jẹ ẹni
tawọn araalu fẹran, to si ti ṣe oriṣiriṣi anfaani fawọn eeyan. Ẹni to ti mu
awọn eeyan kuro ninu iṣẹ ati oṣi ni, to si tun sunmọn awọn eeyan daadaa lai ṣe
ojuṣaaju ẹnikẹni.
No comments:
Post a Comment