Nitori owo oṣu ti mo n
gba lọwọ Ijọba ni mo ṣe n tẹle Ọnarebu Akinlade ti Gomina Amosun fa kalẹ – Ọba Akamọ
Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Ọba Abdulfatai Akorede Akamọ to jẹ
Olu-Itori tiluu Itori-Ẹgba nipinlẹ Ogun ti sọ ọ sita gbangba pe Ọọni Ile-Ifẹ,
Ọba Adeyẹye Ogunwusi; Aare Ọna Kakanfọ, Ọtunba Gani Adams ati Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ lo n ba aṣa ati
iṣe ilẹ Yoruba jẹ latari bi wọn ṣe n rin awọn iri ti ko tọ, paapaa bi wọn tun ṣe n ṣagbatẹru awọn oloṣelu kaakiri, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.
Kabiyesi naa sọ pe bi nnkan ṣe bajẹ lagbooole awọn
lọbalọba lasiko yi, ko ṣẹyin Ọọni Ile-Ifẹ ati Ọba Alake, paapaa Aarẹ Ọna
Kakanfọ ati latari bo ṣe lọọ gbe awọn oye ti wọn ti pa ti dide.
Laipẹ yi ni Ọba Akamọ sọrọ naa lasiko to n bawọn akoroyin
kan sọrọ ninu Aafin ẹ to fikalẹ siluu Itori, nibi to ti sọrọ nipa ayẹyẹ ọdun
mẹẹdogun to ti dori oye naa gẹgẹ bi Kabiyesi, eyi ti oo waye laipẹ yii.
Bakan naa lo tun sọrọ nipa oṣelu to n lọ nipinlẹ Ogun
lọwọlọwọ, O ni bii kii ba a ṣe ti owo oṣu toun n gba lọwọ ijọba ipinlẹ Ogun
labẹ gomina Ibikunle Amosun ni, oun ki ba ti duro lori ọwọ oun lati ma ṣe oṣelu
rara, nitori pe oṣelu kii ṣe nnkan to yẹ kawọn ọba maa da si.
Lọpọ igba ni Ọba Akorede Akamọ ti jẹ ko di mimọ nita
gbangba pe, ko sẹni toun yoo dibo oun fun bi ko ṣe Ọnarebu Abdulkabir Adekunle
Akinlade ti ẹgbẹ oṣelu APM, eyi ti Gomina ipinlẹ naa fa kelẹ, to si tun tẹle
wọn lọ sawọn ibi ipolongo idibo kaakiri.
Pupọ ninu awọn to n ri Ọba Akamọ ni wọn ko ṣe iye meji pe
ẹgbẹ oṣelu APC ati APM ti gomina Amosun ati Ọnarebu Akinlade n ṣe loun naa n ba
wọn ṣe, kii tun un ṣe oun nikan, Kabiyesi atawọn Ọba yooku ni wọn n tẹle Gomina
kaakiri.
Ninu ọrọ Ọba Akamọ, o sọ pe “Onikaluku lo ni ọna ti wọn
gba wo nnkan, bi ẹ ba kọ ẹẹfa kalẹ, ẹẹfa lo maa jẹ lọdọ mi, ṣugbọn ẹẹsan-an ni
yoo jẹ lọdọ yin. Gẹgẹ bi Ọba alade, ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni ri ẹ nibi too fi si,
aya fi ti o ba fẹ ki wọn tan ẹ je, ti o ba si jẹ ki wọn ta ẹ jẹ, a jẹ pe bi o
ba ṣe tẹ ibusun rẹ naa lo ṣe maa sun le.
“Ko sẹni to too gbe oju rẹ wo Gomina, yala, o fẹ ẹ, tabi
o ko fẹ ẹ, ko si nnkan ta a fẹ ẹ ṣe sii. Awa Ọba wa labẹ owo ti gomina n san
sita fawọn oṣiṣẹ, oṣiṣẹ lawa Ọba naa jẹ, Gomina lo si n san owo osu fun wa.
Oṣelu idagbasoke ni mo n ṣe e, ẹ gbagbe nipa ṣiṣe oṣelu oju-ṣaaju.
“Bi eeyan kan ba n ṣe nnkan to dara, ẹ jẹ ka jẹ ki iru
ẹni bẹẹ mọ, ka si gbe oṣuba kare fun un, bi eeyan ba si n ṣe nnkan to ku diẹ
kaato, ẹ jẹ ka sọ fun un. Ṣugbọn ẹyin naa, ẹ lọ ọ sọ fun gomina pe nnkan to n
ṣe ko dara, ki ẹ wa ri iya to maa jẹ yin.
“Iṣoro ta a ni ni pe, awọn eeyan wa mọ nnkan to yẹ lati
ṣe, ṣgbọn ibeere to wa nibẹ ni pe, ṣe gbogbo igba ni wọn n ṣe e. Ninu iran mi,
paapaa iran awọn baba-nla mi, latigba ti wọn ti sa ipinlẹ Ogun silẹ, ko tii
gomina to gboju-gboya bii Gomina Amosun ri, ẹ jẹ ka sọ otitọ to wa nibẹ, ti a
ba si n sọ pe itẹsiwaju ninu ijọba, ẹ ma gbagbe pe ko nii tẹ awọn kan lọrun,
nitori pe iru ẹni to n sọrọ nipa itẹsiwaju naa ba awọn eeyan ninu ẹgbẹ ni, wọn
maa fẹ ki nnkan maa lọ gẹgẹ bo ṣe n lọ.
“Ṣugbọn Gomina sọ pe rara, ko ri bẹ ẹ, ipinu idagbasoke
ati ilọsiwaju (Mission to Rebuild) ni. Gbogbo eeyan ni mo wa fun un, mi
o si fun ẹnikan ṣoṣo, yala Dapọ Abiodun ni, tabi adije yoowu. Laipẹ yi ṣi ni
Ọnarebu Ladi Adebutu ṣi wa sọdọ mi lati ba mi sọrọ, mo tẹwọ gba a.”
Nipa gbigbagbọ ninu itẹsiwaju, Ọba Abdulfatai Akorede
Akamọ sọ pe “Nnkan to dara ju, to si le gbe wa de ilẹ ileri niyẹn. Ẹ lọ ọ wo
ipinlẹ Eko, bi ko ba si itẹsiwaju nipinlẹ Eko, awọn eeyan ko ni maa jẹ igbadun
ti wọn ri jẹ lonii, ẹ ma jẹ ka tan ara wa jẹ, ṣugbọn nnkan to n kan mi lominu
ni pe, a ko laju, a si tun n ṣebi ẹni ti ko laju. O digba ti a ba ṣugbaa ara
wa, ti a si fọwọsowọpọ, ka to le sun oke kuro nibi to wa. Oke gan an fẹ awọn ti
yoo sun oun, ṣgbọn ko ri.
“Itẹsiwaju ti a wa n sọrọ nipa ẹ yi, kii ṣe fun awa, bi
ko ṣe fun awọn iran to n bọ lẹyin wa. Bi ẹ ba wo nnkan to n ṣẹlẹ lagbo awọn
lọbalọba wa lonii, a maa ri i pe gbogbo nnkan lo ti bajẹ kọja aala. Lati ori
Ọni Ile Ifẹ, ẹni to yẹ ko jẹ baba gbogbo ilẹ Yoruba, oun gan an lo ba gbogbo ẹ
jẹ patapata, ki lo de ti iru nnkan bẹẹ fi n ṣẹlẹ.
“Laipẹ yi ni Ọtunba Gani Adams ti wọn n pe Aarẹ Ọna
Kakanfọ bẹrẹ sii fawọn eeyan jẹ oye, to n da awọn oloye ti ko yẹ pada sipo, ko
ye mi rara, iru ọpọlọ ti a ni lati maa fi ṣe nnkan, paapaa ọna ti a n gba huwa
loriṣiriṣiri, nibo ni oloye ti n fi oloye jẹ.
“Ṣe emi nikan ni Ọba to wa nipinlẹ Ogun ni, ṣe owo oṣu
lọdọ ijọba ipinlẹ Ogun yato si tawọn Ọba tọrọ kan ni, ki lo wa a de to fi jẹ pe
emi nikan ni gbogbo eeyan da oju bo. Ṣugbọn nnkan ti mo mọ daju ni pe agbajọwọ
lo le ko okuta soju kan. Ẹ jẹ ka dide lori ibusun wa, ka la oju wa, ẹbun
ififun-ni wa ninu wa, idi yi ti a k fi le kuro loju kan ṣoṣo. Bi o ba ṣe nnkan
ti ko dara, ki lo de ti a ko le bẹbẹ, ti Ọlọrun to da wa ba le bẹbẹ, melo-melo
wa ni awa ẹlẹran ara.”
Nipa ti Alake, bẹ o ba gbagbe, lai pẹ yi gomina Ibikule
Amosun mu Ọba Gbadebọ atawọn Ọba kan lọ sọdọ Aarẹ Buhari lati loo sọ pe
Akinlade lawọn fẹ ẹ ṣiṣẹ fun, eyi lo si da oriṣiriṣi ariyanjiyan silẹ nipa
bawọn gomina ṣe n lo awọn Ọba fun oṣelu.
Olu-Itori ni “A ni lati pada sijọba tawọn Ọba yoo ti maa
paṣẹ, igba ti a ba too pada sijọba tawọn Ọba yoo ti maa paṣẹ lawọn Ọba too le
lẹnu ọrọ. Ko si ipo eyikeyi ti ẹ ba fun awọn Ọba lasiko ijọba awaarawa yi, a
kan an tan ara wa jẹ lasan ni. Ninu iwe ofin wa lonii, ipo oludamọnran lawa Ọba
wa, o si ṣugbọn ninu, iyẹn ni pe Ọba ti wọn ba pe fun amọnran.
“Nigba ti Gomina ranṣẹ pe Ọba Gbadebọ pe ko tẹle oun lọ
siluu Abuja, kilo de to fi tẹle lọ, ko yẹ ko lọ rara. Gomina ko pe Ọba min in
yatọ si Alake. Ko da a, lai pẹ yi, Ọba Awujalẹ tilẹ Ijẹbu sọ ọ pe Ọmọba Dapọ
Abiọdun loun yoo ṣiṣẹ fun, fun idi eyi, ani lati maa ṣe oun gbogbo
niwọntunwọnsi.”
No comments:
Post a Comment