OGUN: WAHALA EGBE OSELU LABOUR ATI ADC TUN GBONA MIN IN YO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 8, 2019

OGUN: WAHALA EGBE OSELU LABOUR ATI ADC TUN GBONA MIN IN YO

...Arabambi soko oro si GNI

...E ma da lohun, alatenuje ni - GNI


Alaga egbe oselu Labour nipinle Ogun, Komureedi Abayomi Arabambi ti bu enu ate lu adije sipo gomina nipinle Ogun labe egbe oselu African Democratic Congress, ADC, Omoba Gboyega Nasiru Isiaka gege bi eni to n wa agbara lonakona.

Kii se pe Komureedi Arabambi to tun je alaga apapo egbe oselu, iyen IPAC nipinle naa dee de soro si Gboyega Isiaka bi ko se bawon igun kan ninu egbe oselu Labour se lawon yoo dide satileyin fun GNI, o ni oun mo pe oro ori ahon lasan ni.

Arabambi lo soro yi nibi ipade to se pelu awon oniroyin ninu ogba awon oniroyin to ni Iwe-Iroyin pelu awon oloye egbe oselu naa atawon adije sipo ninu egbe naa.

O ni inu o baje lori bi Gboyega Isiaka se gbawon alagabagebe inu egbe oselu Labour laaye lati tan an je, toun naa si gba won laaye.

Arabambi to ni lai pe yi nile ejo giga apapo niluu Abeokuta ti pase pe awon ko bu owo lu Ogbeni Oginni Olaposi ati Sunday Owolabi lati wa ninu egbe naa, nitori pea won ni won n da egbe ru, fun idi eyi, awon mejeeji yi ni won lo n foruko egbe oselu Labour lu awon eeyan ni jibiti, ti won si n ba oruko egbe naa je kaakiri.

Iyalenu lo je pe ki oro ti Arabambi so yi too jade sita ni Gboyega Isiaka funra e ti daa lohun pada pe alatenuje ni alaga egbe oselu Labour naa, iyen Komureedi Arabambi, toun ko si setan lati maa ba a fa oro.

Agbenuso fun GNI, Ogbeni Bolaji Adeniyi lo gba enu oga e soro naa jade sita pee ni to ye kawon eeyan maa kaanu e ni Arabambi nitori pe oro e ko ye ara e mo, nitori naa, awon ko setan lati da a lohun, ati pe eni to maa fi ko oro so lo n wa.

Awon to tele Komureedi Arabambi wa sibi ipade awon oniroyin naa ni; Barr. Oyenekan Akingbade ati adije sipo gomina labe egbe naa, Arabinrin Modupeola Sanyaolu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI