OGUN: KAṢAMU NI AJỌ INEC FỌWỌ SI GẸGẸ BII ADIJE SIPO GOMINA LABẸ ẸGBẸ OṢELU PDP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 18, 2019

OGUN: KAṢAMU NI AJỌ INEC FỌWỌ SI GẸGẸ BII ADIJE SIPO GOMINA LABẸ ẸGBẸ OṢELU PDP

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, inu idunnu ati ayọ ni Sẹnetọ Buruji Kaṣamu wa latari bi orukọ rẹ ṣe jade ninu orukọ awọn adije sipo gomina lorileede Naijiria lọdun 2019 ta a wa yii, ti wọn ko si ronu kan Ọnarebu ladi Adebutu toun ti na obitibiti owo lati rii pe oun ni wọn pada fa kalẹ gẹgẹ bi adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.


Bo tilẹ jẹ pe lai pe yi niSẹnetọ Kaṣamu ti pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa pe ki wọn darapọ di ẹyọkan ṣoṣo, eyi ti ọpọlọpọ awọn iwe iroyin gbe e pe Kaṣamu ti gba lati jẹ ki Adebutu di adije, ṣugbon ti wọn pada sọ pe ko ri bẹ mọ.

Lọjọ Tọside ana ni ajọ INEC gbe awọn orukọ naa jade sita, fawọn ọmọ Naijiria, to si jẹ iyalẹnu pe orukọ Kaṣamu ni wọn fi sita gẹgẹ bi ẹni ti ẹgbẹ oṣelu PDP fa kalẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI