Bọsun Ọlaniyi,
Abeokuta
Bi wọn ba n sọ nipa awọn abiyamọ tootọ, to ko
awọn eeyan mọra, to n ṣaanu fawọn alaini, paapaa awọn to ni ipenija ara, odu ni
Oloye Arabinrin Jackie Adunni Kassim, kii ṣaimọ foloko.
Bo ṣe n ṣe fun onile, bẹẹ lo n ṣe fun alejo, ko
da a, awọn to sunmọn ọn ko ye e royin iwa rere ẹ laarin awujọ, idi ni yii ta a
gbọ pe awọn agbaagbaa laarin ilu fi panupọ pe ki wọn yan Oloye Arabinrin Adunni
Kassim gẹgẹ bi Iyalode ilu Igbore, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
Latigba ti Arabinrin Adunni Kassim ti di Iyalode
ilu Igbore ni nnkan bi ọdun meloo kan sẹyin, ko sẹni to royin ẹ laburu, ko si
sẹni ti kii gbe oṣuba kare fun un nitori ti wọn lo n fi iwa olori han, ti iwa
ọmọluabi ara ẹ naa ko ye e pokiki ẹ kaakiri.
Arabinrin Adunni Kassim to tun jẹ Dokita, ẹni ti
ọpọ awọn eeyan mọ si IYADUNNI pẹlu iwadii ti a ṣe la ti gbọ pe awọn agbaagba
nipinlẹ Ogun ni wọn fọwọ sọya lori ẹ pe ko jade fun ipo gomina ipinlẹ Ogun, ko
si lọọ ja fun ẹtọ awọn araalu.
Lọjọ Mọnde to kọja yi ni Iyadunni lọ siluu Ọta,
nijọba ibilẹ Ọta lati lọọ bawọn eeyan sọrọ nipa ipinu ẹ lati jade du ipo naa,
labẹ ẹgbẹ oṣelu United Democratic Party, UDP, ẹgbẹ to n ṣe agbelarugẹ iṣọkan
ati ifẹ laarin ilu.
Lọjọ Mọnde naa, ẹsẹ ko gbero lori papa ti wọn lo
nitori pe ṣe ni gbogbo agbegbe naa kun fọnfọn, tawọn eeyan si n sọ ohun rere
nipa Arabinrin naa, ko da a, tawọn kan n sọ pe Iyadunni nikan lo le ṣe nnkan
tawọn araalu n fẹ fun wọn.
Bi a ko ba parọ, igba akọkọ lọjọ Mọnde, ọjọ
kejidinlọgbọ oṣu kinni ọdun 2019 ti aṣojukọroyin AWIKONKO, Bọsun Ọlanrewaju yoo
ri ibi tawọn alaabọ ara ti pọ to bẹẹ, ko ti ẹ yeeyan boya wọn ni ẹgbẹ ni,
ṣugbọn ohun ti gbogbo wọn n sọ ni pe awọn ko le gbagbe ohun rere ti Iyadunni ti
ṣe fawọn, tawọn si ṣetan lati gbaruku ti obinrin naa gẹgẹ bi abiyamọ to n gbọ
igbe awọn eeyan.
Nigba toun funra ẹ n sọrọ, Oloye-Dokita-Arabinrin
Jackie Adunni sọ pe ko si nnkan meji to mu koun gba lati jade dupo gomina bi ko
ṣe awọn ipinu rere toun ni fawọn eeyan, paapaa awọn ọmọ bibi ipinlẹ Ogun.
O ṣeleri pe gẹgẹ bi obinrin, oun ko nii
ṣoju-ṣaaju lati ṣiṣẹ idagbasoke siluu kan ṣo’so bii tijọba to wa nita lonii, o
ni gbogbo agbegbe patapata to wa nipinlẹ Ogun loun yoo ṣiṣẹ idagbasoke de, toun
yoo si ṣe awọn ọna igberiko kaakiri.
O ni lara awọn nnkan toun ni lọkan lati ṣe ni Eto
Ilera to peye nibi tawọn to ba ni ipenija ara yoo ti jẹ anfaani alailẹgbẹ, ati
pe awọn to ba n ṣaisan gan an ko nilo lati da ara wọn laamu mọ nipa lilọ
kaakiri lai ri itọju, nitori pe gbogbo ọsibitu loun yoo tun ṣe, toun yoo si ro
awọn oṣiṣẹ lagbara.
Eto Ẹkọ alailẹgbẹ ni ipinu keji to loun ni lọkan
lati ṣe, nitori pe kii ṣe ahesọ wipe eto ẹkọ ipinlẹ Ogun ti dorikodo, to si
nilo keeyan tete mojuto. Jackie Adunni tẹnumọ ọn pe ibanujẹ ọkanlo maa n jẹ
foun nigba toun ba ri bawọn ileewe to jẹ tijọna ṣe ri, to jẹ pe ilẹẹlẹ lawọn
akẹkọọ ti n kẹkọọ, ṣugbọn gbogbo ẹ ni yoo yatọ lasiko ijọba toun.
Eto Aabo to wa larọwọto jẹ ọkan pataki nnkan toun
fẹẹ ṣe. Agbegbe to ṣee mu yangan jẹ Iyadunni logun pupọ, ti yoo si mu kawọn
eeyan maa gbe ninu ilera to peye.
Atunṣe gbogbo ibi igbafẹ, igbelarugẹ aṣa atawọn
nnkan idaraya to ṣee mu yangan, idagbasoke Iṣe Agbẹ, ati iṣejọba ti ko lafiwe,
iṣejọba ti kii fi nnkan pamọ fawọn araalu wa lara eto ti abiyamọ naa n gbe bọ
wa fawọn araalu. O wa a ku sawọn araalu lọwọ lati yan laari igbekun ati
itusilẹ. O ku sawọn araalu lọwọ lati yan adari gidi, ki wọn si dẹkun lati maa dibo
fun awọn oloṣelu ẹlẹtanjẹ.
No comments:
Post a Comment