Buhari |
Bo tilẹ jẹ
pe ijọba apapọ orileede yi ti paṣẹ pe ki wọn fagile ẹsun ti wọn fi kan adajọ
agba lorileede yi, Onidajọ Walter Onnoghen latari pe ko sọ awọn dukia to ni
sita, ati pe o lọwọ ninu awọn ẹsun iwa gbigba abẹtẹlẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Akwa-Ibọm,
eyi ti ajọ EFCC fi kan an .
Igbakeji Aarẹ
orileede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti pariwo sita fawọn ọmọ Naijiria pe
Aarẹ Muhammadu Buhari ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti won fi gbe adajọ agba tẹlẹri
lorileede yi, Onidajọ Walter Onnoghen lọ sile ẹjọ Tribunal lọjọ Satide to kọja
yi.
Ọṣinbajo lo
sọrọ naa nibi ipade gbogboogbo ọlọjọ kan to ṣe pẹlu awọn akọroyin ori ẹrọ
ayelujara lọjọ Wẹside ana niluu Abuja, iyẹn Online Publishers Association of Nigeria eyi ti wọn pe akori ẹ ni “Gbigba iroyin laaye lai figbakan bo ọkan ninu,
ninu eto idibo ọdun 2019, (Free Press and objective reporting in the
2019 election year.)
No comments:
Post a Comment