Bọsun
Ọlaniyi, Abeokuta
Adije sipo
gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu United Democratic Party, UDP nipinlẹ Ogun, Dokita
Arabinrin Jackie Adunni Kassim ti sọ ọ di mi mọ pe o da oun loju lati di gomina
ipinlẹ naa lọdun 2019 ti a wa yi.
Laipẹ yi ni
Arabinrin Adunni Kassim sọrọ naa niluu Abẹokuta lasiko to gba ẹnu alakoso fọrọ iroyin ati bo ṣe n lọ ẹ, Ọgbẹni Fẹmi Oyewẹsọ sọrọ
nipa ipinu ẹ lati jade dupo gomina, paapaa bo tun ṣe jẹ obinrin. O sọ pe looto
loun jẹ obinrin, ṣugbọn iyẹn ko ni koun ma jawe olubori ninu idibo to n bọ yi.
Oyewẹsọ sọ pe, obinrin naa ni yoo jẹ obinrin akọkọ ninu itan ipinlẹ Ogun lati di gomina, ọdun
yi si ni yoo jẹ pẹlu ogo Ọlọrun, ti ko si si nnkan to le yẹ ẹ.
O tun jẹ ko
ye wa pe latigba ti wọn ti da ipinlẹ naa silẹ, ko tii si obinrin to dari akoso
ipinle naa, to si jẹ pe awọn ọkunrin ti wọn n yan sipo lati sakoso ni wọn ko ṣe
awọn nnkan to yẹ lati mu igbe aye irọrun de fawọn araalu.
Jackie
Adunni Kassim tun ni bo tilẹ jẹ pe oun ti bẹrẹ ipolongo idibo naa lati ojule
si ojule, agbegbe si agbegbe, toun si n bawọn eeyan sọrọ, ti wọn si n fọkan oun
balẹ, o daju pe oun yoo jawe olubori
Nigba to n
sọ nnkan meje pataki to fẹ ẹ ṣe fawọn ọmọ ipinlẹ naa, Adunni Kassim sọ pe “Eto
ilera to peye, irolagbara awọn eeyan, eto ẹkọ to peregede, eto aabo to peye, agbegbe
ti yoo mu ilera gidi wọlu, iṣejọba ti kii ṣoju-ṣaaju, titun awọn ibi igbafẹ ati
aṣa ṣe, pẹlu awọn min in lo wa nilẹ ti mo fẹẹ ṣe.
“O dami loju
pe lọjọ keji oṣe kẹta ọdun yi, emi ni ajọ eleto idibo, iyẹn INEC yoo kede gẹgẹ
bi ẹni to jawe olubori, nitori pe gbogbo awọn araalu ni wọn ti fọkan mi balẹ,
ti wọn si rii daju pe emi gan an lẹni to kaju oṣuwọn lati ṣe e.”
No comments:
Post a Comment