NITORI OWU, JIBRIN LU IYAWO Ẹ PA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 30, 2019

NITORI OWU, JIBRIN LU IYAWO Ẹ PA





Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Boroboro ni baale ile ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Jibrin Abu nka lọgba ọlọpaa nigba tọwọ palaba ẹ segi lẹyin to fi igi lu iyawo ẹ, Victoria Aliyu pa latari owu jijẹ.

Jibrin, ọmọ bibi abule Dabogi niluu Lapai, ijọba ibilẹ Lapai, ipinlẹ Niger la gbọ pe o ti pẹ to ti n kilọ fun Victoria pe ko rọra maa ṣe latari bo ṣe n yan ale, ṣugbọn ti wọn niyen ko gbọ.

Nibi to le de, a gbọ pe Victoria tun n pin kinni abẹ ẹ fawọn ọrẹ ọkọ ẹ, Jibrin yi, to si ti ka a laimọye igba, ti wọn lawọn ara adugbo si maa n pe e ni aja.

AWIKONKO gbọ pe nigba ti Jibrin maa lu Victoria pa, ọkan lara awọn ọkunrin to n ko kaakiri la gbọ pe o pe e lọjọ Mọnde to kọja yi, to si kilọ fun un pe ko ṣọra ẹ, nigba ti ko gbọ la gbọ pe Jibrin fibinu mu igi ọwọ ẹ, to si fi luu titi to fi ku.

Nigba to jẹwọ ẹṣẹ ẹ lọgba ọlọpaa, Jibrin ni lootọ loun lu iyawo oun pa, ati pe lati pa itiju iwa agbere Victoria rẹ lo jẹ koun ṣe bẹẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹnu Muhammad Abubakar fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, oun lo si jẹ ko ye wa pe lẹyin ti Jibrin lu iyawo ẹ pa tan, o gbiyanju lati gbẹmi ara ẹ naa, ṣugbọn tawọn araale ko gba fun un.

O wa ṣeleri pe laipẹ yi lawọn yoo foju ẹ bale ẹjọ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI