NITORI IKU EEYAN MẸẸDOGUN, KABIYESI WAJA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 17, 2019

NITORI IKU EEYAN MẸẸDOGUN, KABIYESI WAJA

Kayeefi lọrọ iku Ọba Michael Oluwafẹmi Aladejana to jẹ Ọba ilu Iworoko nipinlẹ Ekiti ṣi n jẹ fawọn eeyan latari bi Kabiyesi naa ṣe gbe ẹmi min in lojiji lẹyin to gbọ nipa ijamba moto to gb'ẹmi awọn eeyan ti ko din ni mẹẹdogun, eyi to ṣẹlẹ lọjọ Satide Abameta to lọ yi.

Aarọ kutukutu ana tii ṣe Wẹside la gbọ pe wọn lọọ tufọ iroyin naa fun Kabiyesi, bo si ṣe gbọrọ naa ni wọn ni Kabiyesi mu idi lọ silẹ.

Bẹ o ba gbagbe, lọjọ Satide naa ni tirela nla kan to ko raisi oṣelu to jẹ ti Sẹnetọ Tayọ Alaṣọadura to n ṣoju Ondo Central ja wọnu ọja igbalode kan nijọba ibilẹ Irẹpọdun/Ifẹlodun, nibi to ti tẹ awọn eeyan pa.

 Bi iroyin naa ṣe tẹ Kabiyesi lọwọ la gbọ pe Ọba naa ṣubu lulẹ, lẹsẹkẹsẹ ni wọn sare gbe e lọ si ọsibitu kan to wa niluu Ado-Ekiti, latigba naa la gbọ pe wọn ti n tọju e ko to o dipe o gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI