Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
Iyalẹnu nla lọrọ naa ṣi n jẹ fawọn ara agbegbe Abule Ẹgba laarọ onii pẹlu bi wọn ṣe ri ẹbọ ti n ka igun laya, eyi ti wọn gbe siwaju ileeṣẹ awọn IKEDC to n ri sọrọ ina mọnamọna l'Eko.
A gbọ pe o ti ọjọ meloo kan tawọn ara Abule Ẹgba ti koju iṣoro aisi ina, eyi ti ko bawọn ara agbegbe naa lara mu.
Laarọ onii la gbọ pe ṣadede ni wọn ba ẹbọ nla lẹnu ọna abawọle ọfiisi IKEDC, pẹlu aworan ọga to n ṣakoso nibẹ. Iṣẹlẹ naa la gbọ pe o ti ko ibẹrubojo ba ọkan awọn oṣiṣẹ nibẹ titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment