MILIỌNU MARUN NAIRA NI FAYỌṢE NAA GBA NINU OWO DASUKI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 22, 2019

MILIỌNU MARUN NAIRA NI FAYỌṢE NAA GBA NINU OWO DASUKI


Titilayọ Agbaje, Eko

Sẹnetọ Musiliu Ọbanikoro ti fẹsun kan Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Peter Ayọdele Fayọṣe pe oun naa gba ninu owo Dasuki pin lasiko oṣelu lọdun 2014. Ilẹ ẹjọ kan to fikalẹ siluu Eko ni Sẹnetọ Ọbanikoro lo ṣigba ayangan naa lasiko to n jẹri niwaju onidajo Mojisọla Ọlatẹrogun lọjọ Monde ana.

Ninu ẹsun owo to fi diẹ din ni biliọnu meje (6.9b) naira, eyi ti ajọ EFCC fi kan gomina tẹlẹ naa lọjọ kejilelogun oṣu kẹwaa ọdun to kọja, nibẹ ni Ọbanikoro ti sọ pe inu apo owo awọn eleto aabo, iyẹn National Security Adviser ni wọn ti pin fun Fayọṣe naa ninu ẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Fayọṣe loun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an, ṣugbọn sibẹ ẹsun ti wọn fi kan an la gbọ pe o tako ofin bi wọn ṣe n lo owo ti ọdun 2011.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI