Ni nnkan bi aago mejila ọsan onii, Tuside ni ileeṣẹ ọlọpaa tu Sẹnetọ Dino
Melaye to n ṣoju ẹkun Kogi West nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja silẹ pe ko
maa lọ lati lọọ tọju ara ẹ latari bo ṣe sọ pe ara oun ko ya ni gbara ti wọn gbe
e.
Bi ẹ ko ba gbagbe, o ti pe ọsẹ meji bayii ti ileeṣẹ ọlọpaa latilu Abuja ti
lọọ gbe Sẹneto Melaye nile ẹ to wa ni Kogi, latari awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Ọkan lara awọn mọlẹbi Dino Melaye lo tu aṣiri naa fawọn oniroyin pe Dino ti
wa nile ẹ, nibi to ti n sinmi wahala to ṣe pẹlu awọn ọlọpaa.
Lọjọ Monde ana ni ile ẹjọ giga tiluu Abuja fun Dino Melaye lanfaani pe ki wọn
gba beeli e, ṣugbọn tawọn ọlọpaa sọ pe ko si nnkan to jọ ọ, ọdọ awọn ni yoo wa
tawọn yoo fi pari iwadii awọn, eyi gan an lo jẹ kawọn ololufẹ ẹ Dino yari kanlẹ
pe afi ki wọn tuu silẹ laarin wakati mẹrinlelogun bi wọn ko ba fẹ wahala.
No comments:
Post a Comment