Ìgbìmọ̀
tó ń wòye bí ètò ìdìbò ṣe ń lọ sí nílẹ̀ wa, Nàíjíríà èyí tó wà lábẹ́ Àjọ Iṣọ̀kan
Ilẹ̀ Yúròòpù (EU) ti sọ ọ di mímọ̀ pé àwọn kò ní ìfẹ́ nínúu ríri i pé adíje tàbí
ẹgbẹ́ òṣèlú kan ló jáwé olúborí nínúu ìdìbò àpapọ̀ tó ń bọ̀.
Alága
ìgbìmọ̀ náà, Maria Arena ló sọ̀rọ̀ yìí fún àwọn akọròyìn ní ìlú Abuja pẹ̀lú
àlàyé pé àfojúsùn àjọ náà ni láti ní àkọsílẹ̀ bí ohun gbogbo ṣe lọ sí nínú ètò
ìdìbò náà.
Ó ní kò
sí ohun tó kan ìgbìmọ̀ náà pẹ̀lú èsì ìdìbọ̀, adíje tí ó wọlé tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú
tó jáwé olúborí bíkòṣe pe àjọ náà rán wọn láti rí i dájú pé wọ́n wòye bí ètò
ìdìbò náà ṣe lọ ní ìrọ̀wọ́ àti ìrọṣẹ̀.
Ó tẹ̀síwájú
pé ìgbìmọ̀ náà kò wà láti ṣègbè lẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí olóṣèlú kankan ṣùgbọ́n
ó jẹ́ ìgbìmọ̀ tó wà lábẹ́ ìdarí àjọ EU èyí tó dúró lóri ìfinimọniyànse àti iṣòótọ́.
Arena
wá gba àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú pàápàá àjọ tó ń ṣètò ìdìbò nílẹ̀ wa, INEC lámọ̀ràn láti
dúró lórí òtítọ́ àti òdodo ní gbogbo ìpele ètò ìdìbò náà kì ò ba lè kẹ́ṣẹjárí pẹ̀lú
àlàyé pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ni yóò mú àwọn ará ìlú ní ìgbẹkàlé nínú iṣẹ́ wọn.
Ó ní
ètò ìdìbò náà ni ó fún gbogbo ọmọ Nàíjíríà ní àǹfàní láti ró ètò iṣèjọba
àwarawa lágbára síi ju ti àtẹyìnwá lọ nítorí náà ni kí àwọn tórọ̀ kàn lórí ètò
ìdìbò náà pàápàá àjọ INEC àti àwọn elétò àbò ṣíṣe wọn bíi iṣẹ́ láti mú ìdìbò náà
lọ ní àlááfíà.
No comments:
Post a Comment