JIDE KOSỌKỌ SAYẸYẸ ỌJỌ IBI ỌDUN MARUNDINLAADỌRIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 17, 2019

JIDE KOSỌKỌ SAYẸYẸ ỌJỌ IBI ỌDUN MARUNDINLAADỌRIN

Ninu ayo nla ni okan pataki ninu awon osere tiata lorile-ede yii wa bayii, iyen Omooba Jide Kosoko.

Ayeye odun marundinlaadorin (65)ni okunrin to gbajumo daadaa bii isana eleta yii n se loke eepe.

 
Bawon ebi se n ba a yo, bee lawon ololufe e atawon akegbe e nidii ise ohun. Ohun kan pataki ti won si n so ni pe, ki Olorun je ki Jide Kosoko tubo lo opo odun si i laye.

Okan lara awon omo baba naa, Sola Kosoko-Abina, toun naa je okan gboogi ninu awon osere tiata atawon aburo e ni won gbe oro ohun sori intaneeti ayelujara, bi won se n ki baba ohun, bee ni won n  sadura fun un, ti awon osere mi-in paapaa naa n ki Omooba Jide Kosoko ku oriire ayajo ojoobi e yii.

Ninu awon osere tiata ti won je laami-laka lorile-ede yii ni Jide Kosoko n se, bi won ti se mo on daadaa ninu sinima Yoruba, bee lo je ojulowo ninu onise sinima ta a ba n so nipa ki a se sinima lede geesi paapaa.

Bi Jide Kosoko se n kopa ribiribi ninu ise sinima, bee lo tun gbaju-gbaja ninu ka polowo fun ileese tabi ki a ba ni se asoju ileese eni nipase ipolowo.

Bi Jide Kosoko se n se daadaa nidii ise sinima yii, bee lawon molebi e paapaa naa ko kere, bere latori iyawo e to doloogbe, Henrietta Kosoko, ti awon omo naa paapaa ko si se fowo ro seyin bayii, iyen Sola Kosoko ati Bidemi Kosoko bakan naa lawon aburo won pelu.

Ju gbogbo e lo, Omooba Jide Kosoko jiya gidi nidii ise sinima, nitori ojo ti n pa igun e bo ojo pe, bee ta a ba n so nipa awon osere ti won n je oro ise naa loni-in, okan  gboogi ni okunrin omo ipinle Eko yii n se

Lati: Magasinni Alore

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI