Titi dasiko ti ẹ n ka iroyin yi, epe buruku lawọn eeyan kaakiri agbaye ṣi n fi baale ile ẹni ọdun mọkanlelogoji, Jẹlili Lawal ṣẹ latari bo ṣe fipa ba iya arugbo ẹni ọdun mejidinlọgọrin (78) sun, to si fa iya naa nidi ya pẹrẹpẹrẹ.
Ọjọ Wẹside ana lawọn ọlọpaa ipinlẹ Eko foju jẹlili ti wọn niṣẹ awakọ lo n ṣe ba ile ẹjọ. Ọjọ kinni-in oṣu yi la gbọ pe ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko foju Jẹlili han fawọn akọroyin ipinlẹ naa.
AWIKONKO gbọ pe iya arugbo naa ni ko mọ ibi to n lọ, eyi lo fa a to fi rawọ ẹbẹ si Jẹlili lai mọ pe erongba buruku ti wa lọkan lati ṣe. Wọn ni nigba ti Jẹlili gbe iya naa de ibi to n lọ, kaka ko ja a ju silẹ, ṣe lo gbe e wọnu ile akọku kan, to si wọ iya arugbo naa wọle, ko too fipa ba a sun nibẹ lai wo ọjọ ori ẹ.
Bo tilẹ jẹ pe Jẹlili sọ pe oun ko jẹbi pẹlu alaye, ṣugbọn ta a gbọ pe Adajọ ile ẹjọ Majisireeti naa, Arabinrin B.O Ọṣunsanmi sọ fun un pe ko tọju alaye e nitori pe ọdaju eeyan ni.
Adajọ naa wa a paṣẹ pe kawọn ọlọpaa ṣi lọ ọ fi Jẹlili pamọ si ọgba Kirikiri titi di ọjọ kejidinlogun oṣu keji ọdun yi ti igbẹjọ min-in yoo waye.
Thursday, January 17, 2019
![](https://1.bp.blogspot.com/-7Kd9qaiRHuA/WaEtZyc70TI/AAAAAAAADsA/7WUYBVoY-UwwjdEP3kDFPvH9htN0dDKgQCLcBGAs/s1600/demo-image.jpg)
JẸLILI TO FIPA BA IYA ARUGBO SUN FOJU BA ILE ẸJỌ
Tags
# KAYEEFI
PIN-IN KAAKIRI
![Author Image](http://blogger.googleusercontent.com/img/b/R29vZ2xl/AVvXsEhEp5mVwjPoRTgJL2znS5sya4MkAyJ1_86zjy1DjWig8pp-m4PO5jDTnHoAi2uYtqEaRPDt7amQQTrEB7DAhefR7Xzf-EyWmE9IAYg9o7HxatB-sdgRL73sy1bGa3kCjw/s220/Awikonko-3d-glass-window-logo-mockup.jpg)
NIPA IROYIN AWIKONKO
KAYEEFI
Tags:
KAYEEFI
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
PÍN-IN KÁÀKIRI
Author Details
Ile-iṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL lo n gbe IROYIN AWIKONKO jade pẹlu ontẹ Ijọba orilẹ-ede Naijiria labẹ ajọ iforukọsilẹ nni, iyẹn CORPORATE AFFAIRS COMMISSION. A fẹ ki ẹyin ti ẹ n ka Iroyin Awikonko mọ daju pe a ko ni i gba ẹnikẹni laaye lati ṣe ẹda iroyin wa, tabi gbe e jade ninu iwe iroyin min in lai gba aṣẹ lọwọ awọn alaṣẹ wa, ẹsẹ ofin la o fi gbe onitọhun. Bẹẹ, a ko ni fẹ ki ẹnikẹni ṣi iroyin wa ka, nitori pe iwadii kikun la n ṣe ka to le gbe iroyin jade, nitori naa, bi ẹ ba ka ifọrọwerọ pẹlu eeyan, ohun ti ẹni naa ba sọ, ki i ṣe awa la sọ ọ, ẹni naa lo sọ bẹẹ. Fun alaye lẹkunrẹrẹ, tabi ipolowo ọja yin, ẹ le kan si wa lori: +2347012342712.
No comments:
Post a Comment