Gomina ipinlẹ
Ogun, Ibikunle Amosun ti ṣeleri pe oun pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun ti ṣetan
lati fọwọsowọpọ pẹli ajọ eleto idibo nipinlẹ naa lati rii pe ko nii si iwa
jagidijagan, toun gbogbo yoo si lọ nirọwọ-irọsẹ.
Amosun lo sọrọ yi
lasiko to n si idanilẹkọ ọlọjọ kan ṣoṣo ti ajọ to n ṣeranlọwọ fawọn ọlọpaa atawọn
araalu, iyẹn Police Community Relations Committee, PCRC gbe kalẹ ninu gbọngan
ayẹyẹ aṣa, Cultural Center niluu Abeokuta lonii.
Nigba to n gba ẹnu
gomina Amosun sọrọ, akọwe ijọba ipinlẹ naa, Taiwo Adeoluwa sọ pe oun mọ pe ajọ
naa ti mura silẹ daadaa, toun si mọ pe ẹru yoo ti maa bawọn araalu nipa wipe
wahala le ṣẹlẹ, ṣugbọn oun mọ pe awọn ọlọpaa yoo ṣe gbogbo eto to ba yẹ lati ṣe
lati rii pẹ alaafia jọba.
Bakan naa nigba
to n gbe oriyin fun ajọ PCRC, Gomina Amosun sọ pe inu oun dun bi ajọ naa ṣe n
gun agba sii, to si jẹ pe awọn gan an nileeṣẹ to n ṣeranlọwó to pọju fawọn ọlọpaa.
O ni nigba ti ajọ naa maa bẹrẹ iṣẹ pẹrẹu, awọn eeyan wọn ko ju ẹgbẹrun meji aabọ
lọ, ṣugbọn ni bayii, wọn ti le lẹgbẹrun lọna ọgọrun.
Eto
naa ṣi n lọ lọwọ. Ẹkunrẹrẹ n bọ laipẹ
No comments:
Post a Comment