Titilayọ Agbaje
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọdọmọkunrin kan, Ọpẹyẹmi Adeleke lori ẹsun
ti wọn fi kan an pe pata oni pata lo n ji ka kaakiri ilu Oṣogbo, paapaa bo tun ṣe
lọọ ji pata gendebinrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Gift ka.
Aago kan oru ọjọ Monde, ọjọ kokanlelogun oṣu kinni ọdun yii lọwọ tẹ Ọpẹyẹmi,
ọmọ ọdun metalelogun naa.
Agbegbe Agọwande niluu Oṣogbo ni Ọpẹyẹmi ti ji awọtẹlẹ naa ka.
Adajọ ile ẹjọ Majisireeti kan l'Oṣogbo, Mary Awodele si ti paṣe bayii pe ki
wọn ju Ọpẹyẹmi s’ẹwọn titi di oṣu to n bọ tidajọ yoo tun waye lori ẹsun ole
jija ti wọn fi kan an.
No comments:
Post a Comment