ILANA ETO OSELU NAIJIRIA TI LE AWON OLOOTO EEYAN SEYIN LATI JADE DUPO - AMOFIN SOMOYE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 14, 2019

ILANA ETO OSELU NAIJIRIA TI LE AWON OLOOTO EEYAN SEYIN LATI JADE DUPO - AMOFIN SOMOYE

Adije sipo omo ile igbimo asoju-sofin to fe e lo soju awon ara agbegbe Abeokuta South niluu Abuja ninu idibo to n bo lona yi, Amofin Kehinde Adebayo Somoye ti seleri pe oun setan lati yi oselu orileede Naijiria kuro nipo to wa si daadaa, eyi ti yoo je kawon araalu maa je igbadun eto oselu awaarawa. Asofin Somoye, omo bibi ilu Iporo Sodeke niluu Abeokuta ni, ilana tawon oloselu orileede yi n lo fi seto oselu ti je kawon olooto eeyan sa seyin lati jade dupo oselu. Lai pe yi ni Amofin Somoye ba AWIKONKO soro niluu Abeokuta, paapaa latari awon eto to ni fawon araalu. E ka iforowero naa siwaju.

BI MO SE JE
Emi ni Amofin (Barr.) Kehinde Adebayo Somoye, ti mo gbe apoti omo ile igbimo asoju-sofin agba niluu Abuja lati loo soju awon eeyan mi to wa lekun Abeokuta South ninu idibo to n bo losu keji odun yi. Maa kan so die ninu itan ara mi fun yin. Omo bibi Iporo-Sodeke ni mi, ibe ni won bi mi si ni osibitu Sacred Heart. Nigba ti mo maa bere ileewe alakobere, won ti gbe baba mi kuro niluu Abeokuta lo siluu Oyo nipinle Oyo, latibe naa la tun ti lo si Ibadan, ka to o tun lo siluu Eko. Ileewe Methodist ni mo lo niluu Eko, mo tun lo ileewe girama ti Methodis bakan naa. Ko pe ni mo tun lo si orileede Amerika lati loo tesiwaju eko mi.

NNKAN TO GBE MI DE IDI OSELU NAIJIRIA
Ko si nnkan meji to gbe mi wa sidi oselu bi ko se pe omo ilu yi ni mo je, ojoojumo la si maa n soro oselu Naijiria lohun yen, bi won se n se e atawon ibi ti won ku si pelu awon nnkan ti ko ye ki won se la n so lorisirisi la n so, nnkan to gbe mi wa niyen pe lasiko oselu tuntun yi, a gbodo da si, nitori pe a ti maa n menu ba a tipe pe ki awa naa ye maa bu enu ate lu awon ijoba, ka ba won da si, ka si le fi apeere rere lele fawon eeyan nipa bi won se n sejoba, nigba to je pe opo igba lati so o, ti won ko se nnkan to yato. Ni Amerika ti mo loo gbe fungba die yi, a ni orisirisi awon agbegbe to je ti omo Naijiria, ti a si n sepade, mo si je omo egbe die lara won. Emi si ni aare awon omo Egba niluu Philadelphia, ni New Jersey naa, a ni United Nigeria Association of New Jersey to je pe emi ni akowe won nibe, bo tile je pe mo ti kowe fipo naa sile losu die seyin latari oselu yi. Nnkan ti mo fe e mu jade nibe ni pe awa naa ti n gbiyanju lati bere sii gbawon eeyan wole pe kawon naa le maa gbe apoti sawon ipo kan nile Amerika, awon die ni won lawon nife sii. Won ni kemi naa wa a jade dupo, mo si maa n so fun won pe mi o se, ati pet i m ba fe e gbe apoti oselu, orileede Naijiria ti mo ti wa ni mo ti maa gbe e. Ko si nnkan meji ti mo fi so bee ni pe gbogbo nnkan lo n lo dee de nile Amerika. Naijiria lo nilo iranlowo ju Amerika lo, ti mo si rii pe awon nnkan temi naa le fi ran orileede mi lowo ni ki n dije dupo lati gbe igbese naa. Awon nnkan ti mo si le se sile Naijiria ju eyi ti mo le se sile Amerika lo.

BOYA OSELU NAIJIRIA MAA SU MI
Igbiyanju ni gbogbo wa n gba, a si gbogbo tera mo lati maa gbiyanju nitori pe mo ni lati da si, ki n si wa ninu e, mo lawon alaforolo, iyen advisers ti won le maa gba mi lamonran to je pe awon to ti wa nidi oselu tipe. Won duro lati gba mi lamonran lati le je ki n maa mo bi won se n se e lori awon ibi ti ko ba ti ye mi, ti a fi maa de ibi ta a n lo.


IDI TI MO FI YAN EGBE OSELU ACCORD LAAYO
Se e ri awon egbe oselu to loruko te e mo yen, ero ti po nibe, bi e ba si loo ba won, se ni won maa so fun un yin pe ki e lo duro fun iye odun kan, o le je odun merin, tabi odun mejo, ti won ko si ni je ki e fi ara yin han fawon eeyan lati je ki won mo iwon ti e gbe. Nigba to ba si so fun e pe asiko ti to, ko ni saaye fun e lati se nnkan to yato si eyi tawon n se, paapaa eeyan ko ni le gbe igbese min in yato si nnkan ti won ba ti so. Bi won se n dibo abele ninu awon egbe oselu wonyii, awon oloye egbe ni won n dibo yan asoju ati adije, won ko si le yan eni to ba n waasu ayipada, tabi ilosiwaju, eeyan to ba mo iro pa daadaa ni won maa n yan. Mo ti lawon ore ti won ti gbiyanju e ri lawon egbe oselu yi, to je pe ijakule ni won n ba pade pelu gbogbo owo ti won na ati wahala won. Leyin gbogbo e, awon baba isale lo yan fun won, ti won ko ri nnkan gbe se. idi ni yii ti mo fi wo o pe ka lo si egbe oselu to je pe mo maa le ri aaye to po lati bawon eeyan soro, mo si ti jere nibe. Egbe oselu Accord ti je ki n jade sita bawon eeyan mi soro, lati je ki won mo awon nnkan ta a ni fun won, eyi tawon egbe nla yi ko le se.

LORI ORO BABA ISALE
Baba isala yato si baba isale, mo fe e le so pe gbogbo egbe oselu patapata ni won n ni awon agbaagba, tonikaluku si mo ipo e bi won ba fe e dari egbe, sugbon tawon egbe oselu nla-nla yi tun peleke debi pe won fe e gba gbogbo agbara patapata, ki won si le maa pase bob a se wun won. A ri nnkan to sele niluu Eko, bi Gomina Ambode se gbiyanju to, won yo o nitori pe awon agbaagba egbe gba pe ko se nnkan to ye ko se. kii se pe won ba a ja lori pe ko tun ilu se, sugbon won n ba ja tori pe owo ilu ti kii se owo ti e, ko gbe e sile fun won lati pin in tabi ko je pe awon ise to ba fe e gbe jade, ko maa gbe fawon agbaagba egbe, eyi ti ko bojumu to. Eyi gan an ni nnkan to tun n sele nipinle Ogun wa yi naa, ti gomina wa, Ibikunle Amosun so pe Onarebu Akinlade lo gbodo wole, toun atawon oloye egbe naa lapapo jo o fi agbara han ara won. Agbara awon toke si bori ti ipinle, sibe ko ni itelorun, lo tun se ni ko lo sinu egbe min in pe dandan ni ko je pe oun lo maa je gomina wa. Gomina to n sagbateru eni to fa kale ninu egbe oselu APM, toun si wa pelu egbe oselu APC, o ye ka mo pe nnkan nbe labe aso. Awon egbe oselu APC ati PDP maa n fe ko je pe awon ni won yoo ni gbogbo agbara lowo. O maa n le lati saseyori. Gbogbo egbe ni won ni ipo, sugbon mo gba pe mo le ba gbogbo eeyan to wa ninu egbe oselu Accord soro, ti won si maa gbo temi.


IPOLONGO IDIBO WA
A ti lo kaakiri, a si tun si n lo kaakiri, bee la tun n polongo lori redio, ta a tun n se iforowero lori redio lati bawon araalu soro, tawon naa si n beere oro lowo wa. Ose ta a mu yi lawon ipolongo min in maa tun bere lara oto, nitori pe awon foto ipolongo naa la tun maa gbe segbe opopona kaakiri kawon eeyan le mo eni ti won maa tele. Bo tile je pe a ti n le awon alemode (posters) kaakiri, eyi to ti e wa a je iyalenu ni pe bi a se n le awon alemode yi, to maa a di ojo keji, awon egbe alatako maa ti fa won ya kuro, won ti le ti won lee lori. Iwa ibaje si n lo kaakiri, ko dawo duro, sugbon sibe, iyen o da wa duro lati ma le min in. a tun si n bawon eeyan wa soro, ti won si n fokan wa bale. Opo awon agbegbe kaakiri, iyen CDC, CDA ati bee bee lo lati loo ri lati ba won soro.

DIE NINU AWON NNKAN TI MO FE E SE
Lakoko naa, ile igbimo asoju-sofin ni mo n lo niluu Abuja, awon nnkan to po ju ta a fe se ni nipa oro ofin, ojuse mi si ni lati rii pe awon ofin ti won n gbe kale je anfaani fawon araalu, ko nii je awon eyi to n mu awon araalu gege bi eru, ko ni je fun anfaani awon oloselu. A gbodo maa fi awon ofin yen siro ara wa. Mo maa rii pe awon ofin yen n se oju rere sawon eeyan mi. nipa ti oro owo, mo maa rii daju pe owo ilu ti won ba gbe sile, tiluu naa lo maa je, ko nii wo apo mi. mi o kii fe e la oro naa mole, nitori pe mo mo pee mi ko ni won maa ko owo fun, lati Abuja ni won ti ma maa gbe ise wa, nnkan ti mo fe e je ko ye awon araalu ni pe kobo ninu owo araalu, mi o nii fowo kan lati na si apo ara mi, ilu la maa fi tun se.

BI OFIN SE LE FI ESE MULE
Owo gbogbo wa lo wa, bo se wa lowo oloselu, araalu naa lo tun wa lowo awon oniroyin. Iru awon nnkan tijoba ba fe e teri e bole, kawon oniroyin tete gbe e sita. O kan seni laanu pe opolopo awon oniroyin ni won kii soro jade sita, nnkan tijoba ba fe ki opolopo won ko jade sita ni won maa ko jade, ti won maa fi otito pamo, opo awon akoroyin ni won ti ta ara won. Isoro ti a n koju lorileede yi ni pe ki ilu yi to o le dara, owo gbogbo wa lo wa, ki awon agbejoro, adajo pariwo sita, kawon ajo aladani pariwo sita; kawon agbenuso atawo ajafeto ominiyan pariwo sita, eyi ko ni faaye gba ioba lati fi nnkan pamo, ti gbogbo wa ba dake, bo se ma maa lo niyen, sugbon emi gege bi asoju, mo ma rii pe iru ofin ti won ba a n se, mo gbodo maa ja lati rii pe ofin kookan nii se pelu ese ti eni kookan ba se lo. Kii se pe keeyan ji buredi, ki won wa a fun un ni ewon odun meta, to si je pe awon to n ji obitibiti owo, leyin o reyin, won ko nii dajo fun un, eyi ti won ba si dajo fun, won le so pe ko wa ninu ile e fun osu mefa lai jade sita, iyen House Arrest, fun idi eyi, mo setan lati ja fawon mekunnu debi pe ese ti won ba se ba ofin ti won fi se e lo.


AMONRAN MI FAWON OLUDIBO
Amonran mi fawon oludibo ni pe ki won dibo fun mi, ki won dibo fun eni to setan lati dibo fun won, ti kii se eni to wa lati se ti ara e. Mo fe ka se ile aye yi gege bi won se n se e, to si maa fun awon eeyan atawon iran to n bo lanfaani lati gbe igbe aye irorun. Awon olooto eeyan ni mo fe maa sagbateru ti mo ba wole, yala lati ijoba ibile ni, mo setan lati ran won lowo, opo awon oloselu ni won ko se iru nnkan be, apo ara won ni won maa ja fun, sugbon emi ko setan lati se oju saaju enikeni nipa iranlowo. Owo oselu han pupo, opo awon to ni erongba rere lati se ilu ni won ko lowo lowo lati jade, nnkan to si n fa owo aago wa seyin ni Naijiria niyen. Ilana eto oselu wa ti le awon olooto seyin lati jade dije dupo nitori pe kii se owo kekere ni won fi n gbe apoti.

OSELU ODUN YI, AWON KAN KO NIGBAGBO NINU AJO INEC
Emi ko le so nipa eni ti won yan fun ajo eleto idibo yen boya molebi Aare Buhari ni, nitori bawon kan se so pe molebi Aare ni, bee lawon kan n so pe ko ri bee, awon kan ni Aare ana, iyn Goodluck Jonathan lo ti yan an tele. Sugbon nipa orisirisi to n lo lori eto idibo, pelu bawon kan se n soro nipa itajesile, opo nnkan lo nilo atunse lorileede yi. Mo mo pe ajo eleto idibo, INEC naa ti gbiyanju agbara won. Ajo INEC odun marun un seyin ti yato si eyi ta a ni bayii, won ko tii ni igboya pe eto naa yoo lo daadaa lai kii se pe won yi ibo, ipenija nla la si ni. O ye ki ajo INEC naa jokoo ki won wo gbogbo nnkan to n sokunfa yiyi ibo bii apeere ni gbogbo awon agbeggbe idibo, won ni awon asoju egbe oselu ti won maa n towo bowe, paapa lati ka esi ibo, eyi maa n faaye sile fun yiyi ibo. Awon min in le gba owo lati yi ibo lodi si eni ti won n soju. Ko ye ki awon asoju egbe oselu maa wa nibi idibo lojo idibo, e je ka wa ona min in to dara, ta a le gba lati ka esi ibo awon oludibo, ko ri bee lawon orileede toku nitori agbekale won yato si ti wa, awa naa gbodo dide si oju ona igbalode. Iru awon agunbaniro ti won maa n lo yen, omode lo po ju ninu won, won le lo won lona odi, ki won ko si won lori, ko ye ko je pe iru awon omode ti won ko tii mo nnkankan lo ye ki won maa lo, a ni awon ojogbon, awon agbaagba ti won ko beru, a ni awon amofin ti won le duro lati sabojuto eto idibo, iru awon yen lo ye kijoba maa lo bi a ba n fe ilosiwaju, kii se awon akekoo lo ye ki won gbe sibe lati maa ka esi ibo. A kan ma maa gbadura, ka si maa nireti pe ki ajo INEC se nnkan to ba ye ni.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI