GOMINA AMOSUN NI KI AWỌN ỌDỌ ṢỌRA FUN JAGIDIJAGAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 17, 2019

GOMINA AMOSUN NI KI AWỌN ỌDỌ ṢỌRA FUN JAGIDIJAGAN

Gomina Ibikunle Amosun tipinlẹ Ogun ti ke gbajare sawọn ọdọ wipe ki wọn ṣọra fawọn oloṣelu ti yoo lo wọn fun iwa jagidijagan lasiko oṣelu to wa nita yii. O ni ki wọn ma ṣe gba oloṣelu eyikeyi laaye lati lo lodi si alaafia to ti n jọba lati bii ọdun mẹjọ sẹyin.

Gomina Amosun sọrọ yi lasiko to n bawọn eeyan sọrọ nijọba ibilẹ Ọpẹji, nibi ipolongo idibo to ṣe lọ sibẹ. nibẹ lo ti sọ pe gbogbo ọna lawọn oloṣelu kan n wa lati rii pe wọn pana alaafia to n jọba nipinlẹ naa.

Bakan naa lo rọ awọn eeyan pe ki wọn tete lọọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn ko too pẹ ju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI