Gomina Ibikunle Amosun tipinlẹ Ogun ti kede sita gbangba
pe oun ti ya eto ati ilana idagbasoke alaadọta ọdun silẹ fun ipinlẹ naa, nitori
naa, ki wọn ma ṣe gba awọn oloṣelu ẹlẹtanjẹ laaye lati rọwọ mu ninu eto idibo
to n bọ lọna yi.
Ana tii ṣe Ọjọru Wẹside ni Gomina Amosun sọrọ yi nibi
ipolongo idibo sẹnetọ to n lọ fun, eyi to ṣe lo sawọn agbegbe bii Ita-Baalẹ si
Adigbẹ, Ọba, Onidundun, Mọkọlọki ati Mowe, eyi to wa nijọba ibilẹ Ọbafẹmi-Owode
nipinlẹ naa. Nibẹ naa ni Gomina Amosun ti tun ti lo anfaani asiko naa polongo
ibo fun Aarẹ Muhammadu Buhari.
O ni
bo tilẹ jẹ pe ko si ijọba ti yoo pari gbogbo iṣẹ ipinlẹ lẹẹkan ṣoṣo, idi ni yii
toun fi ya eto ati ilana naa silẹ fawọn ijọba ti yoo de lẹyin toun ba kuro lori
ipo.
Bakan naa lo rọ
awọn araalu lati tete jade lọọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn ki asiko to o lọ.
No comments:
Post a Comment