Nígbà
ayé rẹ̀, Alàgbà Àrágbayé ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi akọ̀ròyìn ìwé-ìròyìn Nigeria Tribune
lábẹ́ gómìnà àná, Lateef Jaknade, kí ó tó darapọ̀ mọ́ ìwé-ìròyìn Sketch lọ́dún
1967 níbi tí ó ti di Olóòtú Ìròyìn Àgbà.
Ọdún
1981 ni wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi akọ̀wé àgbà fún ètò ìròyìn lábẹ́ Olóògbé
Adékúnlé Ajásin, ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Ondo.
Alàgbà
Bọ́lá Àrágbayé pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gọrin ní ọjọ́ kẹ̀wàá oṣù kọ̀kànlá, ọdun
2018, ó sì fi ìyàwó, ọmọ, ọmọọmọ àti àwọn mọ̀lẹ́bí sílẹ̀ sáyé lọ.
No comments:
Post a Comment