FÁYẸMI YÓÒ ṢAYẸYẸ ỌGỌ́RÙN-ÙN ỌJỌ́ ÀKỌ́KỌ́ RẸ̀ LÓRÍ OYÈ LỌ́LA PẸ̀LÚ ORÍSÌÍRÍSÌÍ ÈTÒ TÓ GBÉ KALẸ̀ FÚN ÀWỌN ARA ÌLÚ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 23, 2019

FÁYẸMI YÓÒ ṢAYẸYẸ ỌGỌ́RÙN-ÙN ỌJỌ́ ÀKỌ́KỌ́ RẸ̀ LÓRÍ OYÈ LỌ́LA PẸ̀LÚ ORÍSÌÍRÍSÌÍ ÈTÒ TÓ GBÉ KALẸ̀ FÚN ÀWỌN ARA ÌLÚ

Ọ̀la òde yìí tíi ṣe Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù yìí ni gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ọmọ̀wé Káyọ̀dé Fáyẹmí yóò síde ètò ìrónilágbára fún ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé díẹ̀ àwọn ọ̀dọ́ Ìpínlẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ara ètò láti ṣààmì ayẹyẹ ọgọ́rùn-ún ọjọ́ tógorí oyè gómìnà.

Ọ̀mọ̀wé Fáyẹmí ni wọ́n búra fún gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkìtì lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹwàá, ọdún 2018 tí yóò sì pé ọgọ́rùn-ún ọjọ́ tí ó ti gorí àga ìjọbà lọ́la.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde kan tí Alága ìpolongo àti ètò ìròyìn fún ìgbìmọ̀ tó ń ṣe kòkáárí ayẹyẹ náà, Ọ̀gbẹ́ni Yínká Oyèbọ́dèé fi síta ṣe sọ, gómìnà Fáyẹmi yóò bá àwọn ará ìlú sọ̀rọ̀ lórí ipò tí ìpínlẹ̀ náà wà nílé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ìpínlẹ̀ náà lÁdó-Èkìtì lọ́jọ́ Alàmísì, ọ̀la.

Ọ̀rọ̀ tí gómìnà yóò sọ yìí ni yóò ṣàtúpalẹ̀ bí ìjọba rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ ìtukọ̀ ìlú láàárín ọgọ́rùn-ún ọjọ́ àkọ́kọ́ rẹ̀ lórí àga ìṣèjọba àti àwọn ètò tí ìjọba rẹ̀ ti là kalẹ̀ fún idàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà.

Lára àwọn ètò tí wọ́n là kalẹ̀ fún ayẹyẹ ọlọ́jọ́ kan yìí ni sísí títì Adó-Iyin tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àti àgbẹ́kalẹ̀ àpérò àwọn tọ́rọ̀kàn ní gbogbo ẹ̀ka iṣàkọ́so ìlú ní ìpìnlẹ̀ náà nínú èyí tí wọn yóò bá Gómìnà Káyọ̀dé Fáyẹmi fìkùnlukùn.

Àwọn ọ̀dọ́ tíye wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fàlélọ́ọ̀dùnrùn-ún tí yóò kópa nínú ètò ìrónilágbára náà èyí tí àjọ tó ń rí sí ìgbanisíṣẹ́ nílẹ̀ wa, National Directorate of Employement (NDE) gbárùkùtì, ni yóò wá láti gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìndínlógún tó wà ní ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà Fáyẹmí tó gbé ayẹyẹ ìsààmi ọgọ́rùn-ún ọjọ́ ìṣẹjọba rẹ̀ lóní gbònkẹ́lẹ́, ṣàlàyé pé àfojúsùn òun ni láti rí i pé Ìpínlẹ̀ Èkìtì tún di ipò rẹ̀ mú nínú àwọn ìpínlẹ̀ tó ń léwájú nínú ètò ẹ̀kọ́, ètò ìlera, ètò ọ̀gbìn, ìdàgbàsọ́kè ọ̀dọ́ àti ipèsè ohun amáyédẹrùn.

Ó ní òun ní igbàgbọ́ pé gbogbo àwọn eròńgbà yìí ni yóò di ṣíṣe nípa gbìgbájúmọ́ àwọn òpó mẹ́rẹ̀rin tí ìjọba rẹ̀ dúró lé lórí.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI