EYI LAWỌN GBAJUMỌ OṢERE-BINRIN TI WỌN FẸ OLOWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 25, 2019

EYI LAWỌN GBAJUMỌ OṢERE-BINRIN TI WỌN FẸ OLOWO

Awọn kan wa ninu awọn oṣere tiata lorileede Naijiria, ti wọn ko nilo lati da ara wọn laamu lati wa owo rara, ati pe kii ṣe gbogbo awọn oṣere tiata orileede yi ni wọn ṣiṣẹ naa lati fi ri owo.

Bo tilẹ jẹ pe nitori owo ati gbajumọ ni pupọ ninu wọn fi n ṣe tiata, ṣugbọn awọn kan wa ninu wọn to jẹ pe lati maa fi pa ironu rẹ, tabi lati maa fi mu inu ara wọn dun ni gbogbo igba, paapaa lati sunmọn ọn awọn eeyan pataki lo mu ki wọn maa ṣe e.

Eyi ni diẹ lara awọn oṣere, paapaa oṣere-binrin ti wọn ko nilo lati da ara wọn laamu ki wọn to o le ri owo jẹun.

DAKORE EGBUSON AKANDE
Odu ni Dakore Egbuson Akande, kii ṣaimọ foloko lagbo awọn oṣere tiata, paapaa ti Nollywood. Bo ṣe rẹwa lọmọbinrin naa lo tun ni agbekalẹ gidi nidi iṣẹ naa, tawọn ololufẹ ẹ si n gba ti ẹ, ti wọn tun n kan saara si i lojoojumọ.

Lọdun 2011 ni Dakore Egbuson Akande ṣe igbeyawo alarinrin pẹlu ọkọ ẹ, Olumide Akande, ọjọ naa larinrin debi i pe gbogbo agbaye lo gbọ nipa ẹ, to si mu ki ẹsẹ ma fi bẹẹ gba ero ninu gbọngan ti wọn lo.

Bi ẹ ko ba mọ, Olumide Akande jẹ akọbi ọkan lara awọn gbajumọ olowo lorileede yi, ẹni to tun ti wa nipo akọkọ ri i gẹgẹ bi ẹni to lowo julọ ni Naijria, Oloye Harry Akande.

CAROLINE DANJUMA
Caroline Danjuma Celebrates Ex-Husband Musa Danjuma 
Ṣe lọrọ fẹẹ le di ariyanjiyan nigba ti gbajumọ oṣere-binrin yi, Caroline Danjuma darapọ mọ ẹgbẹ awọn oṣere lorileede yi, iyẹn Nollywood. Bawọn kan ṣe n sọ pe kii ṣe ọmọ Naijiria, bẹẹ lawọn kan n sọ pe ọmọ orileede Spain ni.

Ko si ojumọ kan ki ẹ ma ri Caroline ninu sinima nigba naa, ṣugbọn nnkan to jẹ kayeefi lasiko kan ni bi ko ṣe sẹni to ri Caroline mọ ninu sinima, tawọn eeyan si n beere pe nibo lo lọ, ko to o di pe awọn eeyan ṣẹṣẹ gbọ pe o ti ṣegbeyawo.

Odu ni Jẹnẹra Theophilus Danjuma, kii ṣaimọ foloko lagbaye, orukọ ẹ si rinlẹ kaakiri daadaa, ọkan lara awọn aburo Jẹnẹra Theophilus Danjuma ni Caroline fẹẹ, iyẹn Ọgbẹni Musa Danjuma to jẹ gbajugbaja olokoowo.

Ọdun 2007 ni Musa Danjuma ṣegbeyawo alarinrin pẹlu Caroline. Ṣugbọn nnkan to fẹ ẹ banujẹ diẹ ni pe igbeyawo naa ko pẹ rara to fi tuka, bo tilẹ jẹ pe ọmọ mẹta nigbeyawo naa bi fun wọn.

ỌMỌTỌLA JỌLAADE-EKEINDE
 
Bi wọn ba n sọ nipa awọn oṣere-binrin to gbajumọ daadaa, tawọn eeyan si n bọwọ fun gidigidi, bi wọn ko ba mu Ọmọtọla gẹgẹ ni ẹni akọkọ, wọn yoo mu gẹgẹ bi ẹnikeji. Oun si lobinrin to ni igbeyawo to pẹ ju laarin awọn obinrin, nitori pe o mọ nnkan ti ọkunrin n fẹẹ.

Bawọn ileeṣẹ ṣe n mu gẹgẹ bi aṣoju wọn, bee lawọn obinrin, paapaa awọn oṣere-binrin naa tun n wo gẹgẹ bi awokọṣẹ. Ko sẹni to le gbagbe bi Ọmọtọla ṣe ṣegbeyawo, nitori pe o ṣi kere jọjọ nigba naa.

Gbajumọ Balogun ori omi ni ọkọ ti Ọmọtọla fẹ, ẹni naa si ni Balogun (Captain) mathew Ekeinde, Ọmọtọla si wa ni ipẹẹrẹ (teenager) nigba to ṣegbeyawo, ko si tii siru igbeyawo naa lati ọdun 2001 nitori pe inu ọkọ baaluu ni wọn ti ṣe e, lori ofurufu si ni.

Ilu Eko ni wọn ti gbera lọ silu Abuja nigba naa. Ko sẹni ti ko mọ pe olowo jaburata lawọn to ba jẹ balogun ori omi, ti ọkọ Ọmọtọla ko si yatọ ninu awọn to lowo julọ.

ZAINBA BALOGUN

 
Ko sọrọ ta a fẹ ẹ fi pọn Zainab le, bo ṣe rẹwa, naa lo jafafa, to tun gboju-gboya, to si mọ nnkan to n ṣe, paapaa laarin awọn ẹlegbẹ ẹ lagbo oṣere. Gbajumọ ni Zainab, paapaa nigba to maa kọkọ foju han ninu orin Naeto C lọdun diẹ sẹyin.

Orin naa la fẹ ẹ le sọ pe o di ilu mọn ọn ka, paapaa nigba to tun di gbajugbaja ṣorọsọrọ tawọn eeyan n fẹẹ ri i.

Bo tilẹ jẹ pe pupọ ninu awọn obinrin ni wọn ma n fẹẹ fi orekunrin wọn han fawọn eeyan, ṣugbọn ti Zainab ko ri bẹẹ, ayafi nigba to di pe o ṣegbeyawo pẹlu gbajumo oniṣowo aladani nni, Dikko Nwachukwu.

Nigba to ṣegbeyawo, o fẹẹ le jẹ pe gbogbo awọn ara agboole oṣere tiata ni wọn peju sibẹ lọjọ naa, nitori pe ọjọ manigbagbe ni.

Dikko Nwachukwu tun jẹ oniṣowo to ni iṣẹ to tun n ṣe leka ọkọ ofurufu, to si tun gba iwe aṣẹ lati da ileeṣẹ ọkọ ofurufu ti ẹ silẹ. Dikko ti fẹ iyawo kan tẹlẹ ko too pade Zainab, ṣugbọn iku lo mu obinrin naa lọ.

MARY REMMY NJOKU
 
Bi ẹ ba sọ pe ọkan lara awọn agba oṣere tiata ni Mary Njoku, ẹ ko jayo pa. Ọdun 2000 lo ti wa nidi iṣẹ tiata, bi wọn ko ti ẹ ma a ka a mọ awọn akọkọ (A-lister).
Ọpọ awọn eeyan lo le ma mọ, ṣugbọn Mary Njoku jẹ iyawo gbajumọ Jason Njoku to ni ileeṣẹ tẹfisan Iroko, iyẹn Iroko TV.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI