EYI LAṢIRI BI WỌN ṢE FI MILIỌNU MEJI NAIRA GBA MC OLUỌMỌ SILẸ LỌSIBITU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 16, 2019

EYI LAṢIRI BI WỌN ṢE FI MILIỌNU MEJI NAIRA GBA MC OLUỌMỌ SILẸ LỌSIBITU


Wọn ti gbe e salọ s'oke okun

Bukunmi Akinọla, Ibadan

Bi kii ba a ṣe pe Ọlọrun si ni ẹmi ọkan lara awọn ọga onimọto niluu Eko lo ni, o ṣe e ṣe ko ti sọda sọrun alakeji latari bi wọn gun un lọrun lọsẹ to kọja nibi ipolongo idibo gomina ti wọn ṣe fun adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, iyẹn Babajide Sanwoolu.

Aṣiri to tu si AWIKONKO lọwọ laipẹ yi jẹ ko ye wa pe alẹ ana tii ṣe Tuside ni wọn gbe Ọgbeni Musiliu Akinsanya, ẹni tawọn eeyan mo si MC Oluọmọ kuro ni Ọsibitu ilu Eko, eyi to wa lagbegbe Ikẹja to wa, ati pe miliọnu meji naira ni wọn fi tọju ẹ ko ma ba a ku fun ọta yọ.

Ohun ta a gbọ ni pe awọn ti wọn n wa gbogbo ọna lati rẹyin Oluọmọ fẹ ẹ fi pa okunrin naa patapata nitori ta a gbọ pe ṣe ni wọn tun un ri finrinfinrin pe awọn kan n fẹ ẹ wọ ọsibitu naa lati pa a patapata, paapaa lẹyin ti wọn lawọn ọlọpaa to n ṣọ ọ ti kuro lẹyin ẹ.

Wọn ni ẹmi Oluọmọ ti ko de mọ lo jẹ ki wọn tete gbe e salọ si oke-okun lati tubọ lọ ọ gba itọju daadaa.

AWIKONKO gbọ pe lati bii ọjọ marun-un sẹyin ni wọn ti n to iwe bi yoo ti rin irin ajo lati salọ kuro lorileede Naijiria. Bo tilẹ jẹ pe iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ara ọkunrin naa ti ya, isinmi rampẹ lo fẹ ẹ lọ ọ ṣe nile Amẹrika.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI