EMI ATI GOMINA AMOSUN KII ṢE MỌLẸBI KAN NA O – AKEEM AMOSUN PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 25, 2019

EMI ATI GOMINA AMOSUN KII ṢE MỌLẸBI KAN NA O – AKEEM AMOSUN PARIWO SITA


Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Adije sipo ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin tiluu Abuja ninu idibo to n bọ labẹ ẹgbẹ oṣelu Alliance for New Nigeria(ANN), Ọnarebu Akeem Amosun ti ke gbajare sita pe kawọn eeyan ye e ro pe mọlẹbi kan naa loun ati gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun, nitori naa, ki wọn dibo foun.

Ọnarebu Akeem Amosun lo sọrọ naa laipẹ yi lasiko to n ba aṣojukọroyin AWIKONKO sọrọ niluu Abẹokuta nibi to ti sọ pe orukọ le jọ ara wọn ṣugbọn ọtọọtọ ni agboole tawọn ti jọ wa.

Ọkunrin naa ni ọmọ bibi ilu Igbore loun ti wa, to si jẹ pe ilu Owu nibi ti Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti wa, nitori naa, ko sibi kankan tawọn ti ba tan.

Gbajumọ oloṣelu to fẹ ẹ lọ ọ ṣoju awọn eeyan Abẹokuta South niluu Abuja naa tẹnumọn ọn pe ko si nnkan meji to n gbe oun jade lọọ ṣoju awọn eeyan oun bi ko ṣe lati mu igbe aye irọrun de ba wọn.

Akeem Amosun to fẹran lati maa ṣaanu awọn eeyan lai ṣe ojuṣaaju ẹnikẹni sọ pe latigba toun ti wa ni ileewe girama loun ti n ṣeranlọwọ fawọn eeyan, ati pe ọpọ igba loun ti lo owo ounjẹ fi ran awọn ẹlegbẹ oun lọwọ ti ebi yoo si maa pa oun.

O loun mọ pe nnkan gidi ni lati maa ran awọn eeyan lọwọ, nitori pe Bibeli ati Kuraani fidi ẹ mulẹ, fun idi eyi, o ni ko si nnkan to le mu oun lati ma ṣe iranlọwọ naa mọ.

Bakan naa lo tun fi kun ọrọ ẹ pe ipe toun ni ninu oṣelu ko ju ti ijọba rere lọ, iyẹn ni pe lati ṣoju awọn eeyan oun daadaa boun ba de ipo naa, nitori pe awọn araalu lo ṣe koko lati tọju wọn, ati pe oun mọ nnkan ti wọn n fẹẹ.

O ni ọpọ igba loun ti lọ ọ bawọn eeyan toun fẹ ẹ lọ ọ ṣoju sọrọ, ti wọn si ri i pe nnkan tawọn ni nilẹ lati ṣe fun wọn, ko tii si oloṣelu to ṣi ṣe iru ẹ rii latigba ti wọn ti da ijọba awaarawa silẹ

Nikẹyin lo rawọ ẹbẹ sawọn araalu, paapaa awọn eeyan e pe ki wọn dakun dibo foun lọjọ idibo nitori pe oun ṣetan lati gbọ gbogbo iṣoro wọn pẹlu ogo Ọlọrun, bẹẹ lo tun gbawọn lamọnran pe ki wọn ma ṣe gba owo lọwọ ẹnikẹni ki wọn to o dibo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI