BAṢỌRUN: Ẹ ṣeun, ileeṣẹ eto aṣa ati igbafẹ ti mo jẹ
oludari ẹ nipinlẹ Ogun lonii, o jẹ ileeṣẹ ti Amofin Ibikunle Amosun n dari ẹ, o
tun jẹ ọkan lara awọn ileeṣẹ to da silẹ nigba ti Gomina Amosun de ijọba lati
gbe aṣa wa larugẹ ati lati jẹ kawọn eeyan mọ nipa eto igbafẹ kaakiri
Naijiria ati kaakiri agbaye. Gbogbo ẹ julọ lagbara Ọlọrun, a n gbiyanju agbara wa lati rii pe a ṣe ju eyi ti a ba nilẹ lọ, mo
si mọ pe Ọlọrun n gbakoso.
AWIKONKO: Bawo ni imurasilẹ ayẹyẹ ọdun ilu ilẹ Afrika t’ọdun yi, paapaa bi ijoọba yi ṣe
n ko igba wọle?
BAṢỌRUN: O ti le ni ọdun kẹta ti a ti bẹrẹ, ayẹyẹ ọdun
kẹrin la fẹ ẹ ṣe lọdun yi, ẹ ma si gbagbe pe gbogbo ọsẹ kẹta ninu oṣu kẹrin ọdọọdun
la maa n ṣe e. Mo fẹ ẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ayẹyẹ naa ti gbẹrẹgẹjigẹ, o ti muna
d’oko daadaa, to jẹ pe gbogbo agbaye ti tẹwọ gba a, gbogbo agbaye ni wọn n fẹ ẹ
wa lati darapọ mọ wa. A ti bẹrẹ ipa kiko nipa ayẹyẹ t’ọdun yi, ti mo si fi n da
a yin loju pe o maa larinrin ju eyi to kọja lọ. Ti ẹ mo ipinlẹ Ogun, ẹ maa rii
pe ipinlẹ to dangajia nipa aṣa ni, awa si la maa n ṣe ipo kinni-in ninu gbogbo
nnkan, a si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko doju iṣẹ wa bo’lẹ, ko si tun d’oju adura ti
wa, a ti bẹrẹ imurasilẹ, ṣugbọn o digba ti asiko ba n sunmọ etile ka too le fi
awọn nnkan ti a ni sita.
AWIKONKO: Ipinlẹ Ogun lo maa n
saba ṣe ipo kinni-in nibi eto ti wọn ba ti lọọ figagbaga, kini lawọn aṣiri aṣeyọri
yii?
BAṢỌRUN: Ko si aṣiri kankan nidi ẹ bi ko ṣe pe nnkan
ti a mọn ọn ṣe niyẹn, nitori pe wọn maa n sọ pe ‘abinibi yatọ si abiliti’, wọn
bi wa mọ aṣa nipinle Ogun ni, ẹni to n dari aṣa ni ilẹ kaarọ-o-jiire-bi, tabi
ki n sọ pe bi ẹ ba maa darukọ awọn to ti dari ọrọ aṣa sẹyin nilẹ Yoruba, ko si
bi ẹ ṣe maa darukọ, ti ẹ ko nii darukọ Hubert Ogunde, nigba ti awọn baba wa yi
ti fi apẹẹrẹ rere le’lẹ fun wa, ki lo wa a de ti a ko nii ṣe ju ti wọn lọ?
AWIKONKO: Gomina ṣeleri lati mọ
ere ti yoo jọ Baba Ogunde lọdun to kọja, ṣugbon a ko tii ri apẹẹrẹ ileri naa,
ki lo fa a?
BAṢỌRUN: Gomina ti ri bi ọrọ ayẹyẹ ọdun ilu yẹn ṣe n
lọ pe o ti n kọja ipinlẹ Ogun nikan nitori pe gbogbo gbaye ni wọn tẹwọ gba a,
ti wọn si n fẹ ẹ wa. A jọ ma maa ṣe e ni, ko si ẹni ti gbọn tan, ti ẹ ba si ayẹyẹ
t’ọdun yi, bi ẹ ba ri awọn ibi ti a ku si, ti ẹ si fi to wa leti, a maa ṣe
ayipada. Ju gbogbo ẹ lọ, nnkan ti mo fẹ ki ẹ mọ daju ni pe ọdun ilu ti de, o si
ti duro sipinlẹ Ogun lati gbe aṣa wa larugẹ ati lati sọ ọ di ibi igbafẹ.
AWIKONKO: Ọdun kẹrin yin lo fẹ ẹ
kogba wọle yi, ki lawọn nnkan aritọka si yin gẹgẹ bi aṣeyọri yin?
BAṢỌRUN: Aṣyọri pọ loriṣiriṣi, paapaa latigba ta a ti
de ori oye yi, gbogbo awọn ti wọn ba wa fun iranlọwọ lati ṣagbatẹru wọn la maa
n gbaruku ti, ti wọn si maa n wo wa gẹgẹ bi awokọṣe, ẹwa ni aṣa, aṣa ni ẹwa, ẹbun
l’obinrin, a tun n ṣe omidan obinrin to je ti aṣa
AWIKONKO: Kọmisana fun ọrọ oyi jijẹ
ati ijọba ibilẹ lẹ jẹ ni saa akọkọ ijọba Gomina Amosun, ṣugbọn ti aṣa ati irin
ajo igbafẹ lẹ jẹ bayii, ipo wo ninu mejeeji lẹ gbadun ju?
BAṢỌRUN: Mejeeji lo dara, ikan wa fawọn lọba-lọba ati ijọba ibilẹ, ekeji jẹ ti aṣa
ati ọrọ igbafẹ, ti a ba si n sọrọ nipa aṣa, awọn lọba-lọba ni wọn muu dani l’agbegbe
won, ijọba ibilẹ ni agbegbe ti mo n sọ yi wa, fun idi eyii, mejeeji lo wọnu ara
wọn, mi o le sọ pe eyi lo dara, mi o si le sọ pe eyi ni ko dara, ọkan kan gbe pẹẹli
ju ọkan lọ ni nitori pe, owo wa ninu ọkan, iyi lo wa ninu ekeji, iyi ati owo bi
ẹ ba wo o, wọn jọ n rin ni. Yoruba si maa n sọ pe bi ẹ ba n wa owo lọ, ti ẹ wa
a pade iyi lọna, afi ki ẹ pada sile nitori pe bi a ba ri owo naa tan, iyi la
maa fi ra. Mejeeji lo ni owo ninu, mejeeji naa lo ni yii, wọn kan pọ ju ara wọn
lọ ni.
AWIKONKO: Ki lamọnran yin fawọn ọmọ ilẹ adulawọ nipa aṣọ ibilẹ wiwọ?
BAṢỌRUN: Amọnran mi ni pe ki wọn dakun-dabọ, lootọ ọtọ
ni ẹsin, ọtọ si ni aṣa, ati pe lootọ ni pe aṣa oyinbo ti wọle tọ wa wa, ṣugbọn
sibẹ, a ko gbọdọ ki aṣa wa parẹ, aṣọ wiwọ jẹ pataki nnkan to n gbe aṣa larugẹ, ki
awọn ẹlẹsin mejeeji to o de silẹ wa, o ni ẹsin ti a n sin-in, ko si si ẹsin
kankan ninu mẹtẹẹta to maa sọ pe ki ẹ wa ta ẹjẹ eeyan silẹ, Ọlọrun kan-naa-an
ni gbogbo wa n sin-in, ẹsin lo kan yatọ. Mo wa n gba gbogbo wa lamọnran pe bi a
ko ba le maa wọ aṣọ ibilẹ wa lojoojumọ, ẹ maa wọ ọ lẹẹmeji laarin ọsẹ, awọn
pasitọ wa ti wọn n sọpe afi kawọ wọ suutu (suit) kawọn to o le waasu lori pẹpẹ
ko ṣe aṣa wa daadaa, wọn ko jẹ apẹẹrẹ rere fawọn ọmọlẹyin wọn nipa gbigbe aṣa
wa larugẹ, bẹẹ na lawọn musulumi, bo tilẹ jẹ pe awọn si maa n we lawaani, ju
gbogbo ẹ lọ, afi ka ṣe e gẹgẹ bi wọn ti n ṣe e, ko le ba a rii bo ti n ri.
AWIKONKO: Asiko oṣelu la wa yi,
ninu ẹgbẹ wo lẹ n ṣe ninu ẹgbẹ oṣelu APC ati APM?
BAṢỌRUN: Looto awuyewuye ti n waye lori ẹ, tawọn
eeyan si n fẹ ẹ mọ ibi ti mo wa ninu ẹgbẹ oṣelu mejeeji yi, ṣugbọn mo n fi
asiko yi sọ fun gbogbo awọn eeyan pe ẹgbẹ oṣelu APC, iyẹn All Progressives
Congress ni emi Baṣọrun Muyiwa Ọladipọ wa, mi o ni ibi ti mo n lọ. Ẹgbẹ oṣelu
APC jẹ ẹgbẹ oṣelu ti baba wa, Oloogbe Ọbafẹmi Awolọwọ bẹrẹ ẹ pẹlu Action Group,
to tun pada di ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy (AD), to tun di ẹgbẹ oṣelu
Social Democratic (SDP) nigba kan, tawọn adari tun wa a ko ara wọn jọ lati sọ ọ
di APC ti gbogbo wa wa bayii, ko si nii bajẹ.
AWIKONKO: Ipolongo idibo lo n lọ lọwọ
yi, ki lo fa a ti ẹ ko fi jade?
BAṢỌRUN: Mo fẹ ẹ jade tẹlẹ fun ipo Gomina ipinlẹ
Ogun, ṣugbọn Ọlọrun lo sọ pe asiko ko tii to, mo si mọ pe lagbara Ọlọrun naa,
mo ṣi maa dari ipinlẹ Ogun ti Ọlọrun ba sọ pe asiko ti to lati di gomina ipinlẹ
Ogun. Ṣugbọn lọwọlọwọ bayii, ẹni ti ẹgbẹ oṣelu wa APC fa silẹ, iyẹn Ọmọba (Dọkita)
Dapọ Abiọdun la maa ṣiṣẹ fun, to si maa wọle lagbara Ọlọrun.
AWIKONKO: Ki lo fa a to fi jẹ pe
Dapọ Abiọdun lẹ tẹle, ti ẹ ko tẹle ẹni ti Gomina Amosun to yan yi gẹgẹ bi Kọmiṣana
fa kalẹ, iyẹn Ọnarebu Adekunle Akinlade?
BAṢỌRUN: Ọga wa ni Gomina Ibikunle Amosun, Ọga mi ni
wọn, Gomina mi si ni wọn, awọn naa si ni wọn yan mi sipo. Lọwọlọwọ bayii, ẹgbẹ
oṣelu APC ni ọga mi, Gomina Ibikunle Amosun wa, APC yẹn lemi ati ogunlọgọ awọn
eeyan naa wa. Yoruba bọ, wọn ni gbogbo wa ko le sun ka kọri sibi kan naa-an, bẹẹ
ni wọn tun n sọ pe atori l’aye nitori pe to ba lu siwaju, o maa tun lu s’ẹyin,
wọn tun ni aye funra ẹ dabii gangan ni, iwaju to kọ eeyan kan, ẹyin lo kọ si ẹnikeji,
o ni nnkan ti ọga mi ri ti wọn fi sọ pe Ọnarebu Akinlade lawọn maa tẹle, o si
ni nnkan ti emi naa ri ti mo fi sọ pe Dapọ Abiọdun ni maa tẹle. Oju ọrun to ẹyẹ
fo lai fi ara kan ara wọn.
AWIKONKO: Pupọ ninu awọn ẹlẹgbẹ
yin gẹgẹ ni Kọmisana ni wọn ti kọwe fipo silẹ, ki lo fa a ti ẹyin si fi suro,
niwọn igba ti ẹ ko tẹle ẹni ti Gomina Amosun fẹ ẹ fa kalẹ?
BAṢỌRUN: Ko si nnkan ti mi o fi k’ọwe fipo silẹ, idi
ni pe APC lo wa n’ijọba, Gomina Amosun ko sọ pe awọn n lọ si APM, wọn
kan sọ pe awọn faramọ adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APM ni. Lọwọlọwọ bi mo ṣe
n ba a yin sọrọ yi, ijọba APC lo wa nipinlẹ Ogun, ibẹ si ni mo wa, to ba wa di ọla,
tijọba Amosun ba sọ pe APM lawọn n lọ, ti ẹ si tun ri mi ninu ẹgbẹ oṣelu APC,
igba yẹn lẹ le lẹnu ọrọ, ṣugbọn ni bayii, APC ti Gomina Amosun wa, lemi naa wa,
igba to ba si wun mi ni mo le sọ pe mo fẹ ẹ kuro.
AWIKONKO: Pẹlu bi ẹ ṣe fi erongba
yin han bayii, ṣe ẹ ko le ro o pe Gomina le yọ yin n’ipo?
BAṢỌRUN: To ba ri bẹ ẹ, a jẹ pe bi ọga mi ṣe fẹ ẹ
niyẹn, ti a ko ba lọ, a kii de, ẹ jẹ ko ṣi digba yẹn naa.
AWIKONKO: Ọrọ amọnran yin fawọn ọmọ ipinlẹ Ogun, paapaa awọn oludibo?
BAṢỌRUN: Amọnran mi fawọn ọmọ ipinlẹ Ogun, paapaa
awon awọn ewe ni pe ki wọn ma ba ara wọn ja. Olori to ba sọ pe ki wọn lo ba oun
pa eeyan, ki wọn lọ ba oun gun ẹnikan l’ọbẹ, ẹ sọ fun un pe ko kọkọ fi ọmọ ẹ
siwaju, ti ẹ ba sọ bẹẹ, awọn naa a ki ọwọ ọmọ wọn bọ asọ. Adari ti ko ni iye,
ti ko bẹru Ọlọrun lo maa ni ki wọn lọ ba oun paayan, ki wọn lọ ba oun da ilu
ru. Ki la gbe ta n gbin, ṣugbọn adari to ba ji laarọ, to ba ro ibi si ẹda ẹgbẹ ẹ,
yatọ si pe ko dije, ki wọn si tẹka fun un, ki ẹnikan wọle, ki ẹnikeji si ja kulẹ,
ko ranti pe oun naa bimọ. Adura ti mo si maa gba lojoojumọ ki n to o jade ni pe
ko ri fun eeyan gẹgẹ bi ero ọkan ẹ si mi. Ọlọrun kii ṣe’ka, ẹ ma jẹ ka maa ran
oniṣẹ iku si ara wa.
No comments:
Post a Comment