Ẹ WOJU OGBOLOGBO ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN TO N FIBỌN JALE KAAKIRI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 25, 2019

Ẹ WOJU OGBOLOGBO ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN TO N FIBỌN JALE KAAKIRI

Kani kii ṣe pe awọn ọdọ agbegbe Rumọla nipinlẹ Rivers ko sun asunpara ni, o ṣee ṣe ki gendekunrin ti ẹ n woju ẹ yi ti salọ pẹlu awọn yooku ẹ ti wọn jọ n fẹgbẹ okunkun jale pẹlu ibọn.

Foonu la gbọ pe gendekunrin ta a ko tii morukọ ẹ dasiko ta a sakojọpọ iroyin yi tan fibọn gba lọwọ ọdọmọbinrin kan toun jẹ akẹkọọ ileewe gbogboniṣe ti Captain Elechi Amadi niluu Port-Harcourt.

Bi wọn ṣe gba foonu naa tan, ti wọn fẹẹ maa salọ la gbọ pe aṣiri wọn tu., tawọn ọdọ to gboya, to wa lagbegbe naa si bẹrẹ sii le wọn.

 
Bo tilẹ jẹ pe awọn yooku raaye salọ, ṣugbọn tọwọ pada tẹ eyi ti ẹ n wo yii, lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti muu lọ teṣan ọlọpaa, nibẹ ni wọn si ti ri ibọn ninu apo ẹ.

Iwadii ṣi n lọ lọwọ, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI