Titi Abubakar |
Òkò ọ̀rọ̀ bí èpè bí àdúrà pé Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí ẹgbẹ́ oṣẹ̀lú All Progressives Congress (APC) jáwé olúborí nínú ìdìbò àpapọ̀ tó ń bọ̀ ni Arabìnrin Títí Abubakar, ẹni tíi ṣe ìyàwó olùdíje sípò Àarẹ lórílẹ̀-èdè yìí lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democractic Party (PDP) sọ síta lọ́jọ́rú àná.
Títí Abubakar
ló sọ èyí ní Ìpínlẹ̀ Ondo níbi ìpolongo kan níbi tí òun gan-an ti ń pe àwọn
obìnrin láti dìbò fún ọkọ rẹ̀, Atiku Abubakar nínú ìdìbò Àarẹ lóṣù tó ń bọ̀.
Ó ṣàlàyé
pé ìjọba Àarẹ Muhammadu Buhari ti já orílẹ̀-èdè yìí kulẹ̀ tí ó sì ń wá gbogbo ọ̀nà
láti borí nínú ìdìbò náà pẹ̀lú ìpè pé kí wọ́n fi ibò wọn já ẹgbẹ́ òṣèlú APC náà
kulẹ̀.
Ó ní
gbogbo ìlérí tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe ni kò wá sí ìmúṣẹ tí ó sì ti bí ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀
wàhálà sí àárin ìlú lẹ́yìí tí wọn kò wá àtúnṣe sí.
Aya Abubakar
fi kun un pé pẹ̀lú bí wọ́n ṣe kùnà láti mú orílẹ̀-èdè yìí dé ìbùté ògo, wọn sì
ń wá gbogbo ọ̀nà láti padà sípò iṣejọba nítorí náà ni ó ṣe yẹ kí àwọn ọmọ
Nàíjíríà fi ìbò wọn gbá wọn sí síta.
Ó wá
rọ àwọn ìyálọ́jà àti àwọn ọ̀dọ́ ìpínlẹ̀ náà láti yẹra nínú títa káàdì ìdìbò wọn
pé àwọn ọmọ égbẹ́ òṣèlú APC kan ń lọ káàkiri láti rà á lọ́wọ́ wọn.
Títí Abubakar
kò sàìrán àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ náà létí láti di ìbò wọn fún ọkọ òun, Atiku Abubakar
pẹ̀lú lààyé pé olóòtọ́ ènìyàn ni tí ó ní ètò rẹrẹ fún orílẹ̀ èdè yìí.
No comments:
Post a Comment