Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
Iyawo Gomina ipinlẹ Ekiti, Erelu Bisi Fayẹmi ti
ke gbajare sawọn obi ati alagbatọ, paapaa awọn obinrin ti wọn ṣe abiyamọ pe ki
wọn ti ọwọ awọn ọkọ atawọn ọmọ wọn bọnu aṣọ lati ma gba wọn laaye lati lọwọ si
iwa jagidijagan lasiko oṣẹlu to wa nita yii.
Ana tii ṣe Wẹside ni Erelu Bisi Fayẹmi sọrọ yi
niluu Abuja nibi ipade awọn adari lobinrin, iyẹn Forum of Women Leaders lẹka
iṣẹ ijọba ati aladani kaakiri orileede yi, eyi ti wọ ṣe lati fi gbe ipa tawọn
obinrin nko nipa iwa alaafia lasiko oṣelu larugẹ.
Agbekalẹ ajọ naa la gbẹ pe ko ṣẹyin ajọ awọn
obinrin ilẹ Amẹrika (UN Women), orileede Naijiria ati igbimọ iṣọkan ilẹ Afrika
lapapọ.
Erelu Fayẹmi sọ pe awọn obinrin le ko ipa to jọju
lasiko oṣelu, paapaa lasiko idibo to n bọ lọna yi nipa fiforukọ silẹ gẹgẹ bi oludibo,
ki wọn si jade lọọ dibo fun ẹni ti ọkan wọn yan, ati paapaa nipa kikilọ fawọn
ọkọ atawọn ọmọ wọn pe ki wọn ma ṣe lọwọ ninu iwa jagidijagan, tabi iwa ipanle
lasiko idibo.
Ninu ọrọ agbẹnusọ obinrin akọkọ nipinlẹ Ekiti,
Erelu Fayẹmi ti amugbalẹgbẹ ẹ lẹka eto iroyin ati bo ṣe n lọ ẹ, Arabinrin Funmi
Ajala ṣe sọ, o ni aṣeyori eto idibo to n bọ lọna yi wa lọwọ ipa tawọn obinrin
kaakiri Naijiria yoo ko.
Idi ni pe, o wa lọwọ bawọn ba ṣe le ṣi awọn ọkọ
atawọn ọmọ wọn lọkan lati ma lọwọ ninu iwa ibajẹ to maa n ṣẹlẹ lasiko idibo,
eyi ti wọn n pe ni Electoral Violence.
Bakan naa lo tun gbawọn to n lo ẹrọ ayelujara
lamọnran ki wọn dẹkun lati maa pin ayederu iroyin kaakiri, nitori pe ijamba to
pọ lo n ṣe layika ati agbegbe wa.
No comments:
Post a Comment