Bọsun
Ọlaniyi, Abeokuta
Adije sipo gomina
nipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Sẹnetọ Buruji
Kaṣamu ti pariwo sita fun igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ naa pe ki wọn bọwọ fun aṣẹ tile
ẹjọ pa pe oun ni adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Ogun, eyi ti ajọ
INEC naa si fọwọ sii pẹluu.
Kaṣamu lo
sọrọ naa lonii lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ nipinlẹ Eko lati tako ọrọ ti
agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Kola Ọlọgbọdiyan sọ laipẹ yi pe Ọnarebu Ladi
Adebutu lawọn mọ gẹgẹ bi adije sipo gomina nipinle Ogun.
Bẹ o ba
gbagbe, lọjọ kẹtadinlogun oṣu yi ni ajọ INEC gbe orukọ awọn adije patapata sita
fawọn araalu lati mọ, eyi to jẹ pe orukọ Kaṣamu ni wọn gbe sita gẹgẹ bi adije
sipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP, paapaa julọ to tun jẹ pe gbogbo awọn orukọ ti wọn
wa labẹ Ọgbẹ Bayọ Dayọ lo tun jade pẹluu.
Kii ṣe
iroyin tuntun mọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti pin si meji tipẹ, bawọn kan ṣe faramọ
alaga igun Ọnarebu Sikirulai Ogundele, bẹẹ lawọn kan fara mọ igbimọ ti ọgbẹni
Bayọ Dayọ n ṣakoso ẹ.
Eyi to n jẹ kayeefi
ni pe Ladi Adebutu lawọn igbimo amuṣẹṣe, iyẹn National Working Committee ẹgbẹ
naa fọwọ si, eyi tawọn kan ko faramọ.
Ṣugbọn lọjọ
Wẹside ni Ọgbẹni Festus Okoye to jẹ Kọmiṣana fọrọ iroyin ati didawọn eeyan
lẹkọọ nipa kaadi idibo fun ajọ INEC sọrọ sita pe Sẹnetọ Buruji Kaṣamu lawọn mọ
gẹgẹ bi adije sipo gomina pẹlu aṣẹ kọọtu to wa lọwọ awọn gẹgẹ ojulowo.
Ọjọ Tọside
ni Ọlọgbọdiyan sọrọ ti ẹ niluu Abuja pe lọpọ igba lawọn ti sọ fun ajọ INEC pe
Adebutu ni ki wọn mu, kii ṣe Kaṣamu, nitori pe awọn ko mọ ọn.
Nigba to n
sọrọ, Kaṣamu ni oun ṣi ni adije sipo gomina lẹgbẹ nipinlẹ Ogun pẹlu aṣẹ tile
ẹjọ pa lọjọ kẹrinla oṣu yi, ti aṣẹ naa si de ajọ INEC ati ẹgbẹ oṣelu PDP.
No comments:
Post a Comment