Ìwádìí
tí àwọn onímọ̀ kan ṣe lórí bí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ń pẹ́ láyé sí ti fidìí rẹ̀
múlẹ̀ pé àwọn ọpẹ́lẹ́ngẹ́ obìnrin tí wọ́n ga dáadáa ní àǹfàní láti pẹ́ dáadáa
láyé kí wọ́n sì lò tó àádọ́rùn-ún ọdún lókè eepẹ̀.
Ìwádìí
náà, èyí tí àjọ ìlera kan gbé sórí ẹ̀rọ ayélujára, fidìí rẹ̀ múlẹ̀ pé lílọ bíbọ̀
ẹ̀dá jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún bí ènìyàn ṣe lè pẹ́ láyé sí nítorí náà ni àwọn ọkùnrin
tí wọn kò jókòó sójú kan fi máa ń pẹ́ díẹ̀ láyé ju àwọn ìyókù lọ.
Wọ́n
ní àwọn obìnrin tótó ẹ́rìndínláàdọ́talélèdẹ́gbẹ̀rún (944) nínú àwọn tí wọ́n lò
fún ìwádìí náà ni ó pé àádọ́rùn-ún ọdún.
Wọ́n
ní àwọn obìnrin náà ni ga nìwọ̀n tó yẹ tí wọn kò sì sanra rara èyí tí kò rí bẹ́ẹ̀
fún àwọn ọkùnrin.
Gẹ́gẹ́
bí ìwádìí ṣe rí báyìí, kí lojú tí ẹ fi rí i? Ṣe ẹ gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ máa ń rí?
Ẹ bá wa dá sí i lórí Whatsapp wa: 07012342712.
No comments:
Post a Comment