Bo tile
je pe Komisana olopaa ipinle Niger ti pase pe ki won tete gbe baale ile kan ti
won loo gun iyawo e pa latari esun agbere to fi kan an, sibe iyalenu nisele
buruku naa si n je fun opo awon eeyan, paapaa awon omo ipinle Niger.
Lojo
Tosde to koja yi la gbo pe awon olopaa ekun Gawu Babangida nijoba ibile Gurara,
ipinle Niger rowo to baale ile kan, Ishaya David, eni odun mokandinlogbon kan,
esun ipaniyan ni won si fi kan an.
Gege
ba a se gbo, o ti pe ti won ni David ati iyawo e, Arabinrin Rifkatu ti maa n lu
ara won, ti won si maa n pariwo di awon araale won leti, sugbon toro naa pada
yiwo lojo Tosde ana, nigba ti won lawon mejeeji tun bere wahala, ti iyawo si
dagbere faye.
Nigba
ti David n so nnkan to sele fawon olopaa, o ni”o ti pe ti mo ti n maa n kilo
fun iyawo mi pe ko ye e tele awon okunrin mo, paapaa ko ye e sise asewo mo
niwon igba to ba mo pe oun fe e duro nile oko.
“Ko
gbo simi lenu, o si maa gberaga simi, to maa n so pe ko si nnkan to fe e sele, ati pe awa mejeeji la ni anfaani lati se nnkan to ba wu wa. Nigba to maa ku, se ni ibi naa gbodi lara mi, ti mo si loo mu obe lati fi gun un pa. igba ti mo gun un tan ni oju mi la."
No comments:
Post a Comment